Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael

external-link copy
19 : 6

قُلۡ أَيُّ شَيۡءٍ أَكۡبَرُ شَهَٰدَةٗۖ قُلِ ٱللَّهُۖ شَهِيدُۢ بَيۡنِي وَبَيۡنَكُمۡۚ وَأُوحِيَ إِلَيَّ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانُ لِأُنذِرَكُم بِهِۦ وَمَنۢ بَلَغَۚ أَئِنَّكُمۡ لَتَشۡهَدُونَ أَنَّ مَعَ ٱللَّهِ ءَالِهَةً أُخۡرَىٰۚ قُل لَّآ أَشۡهَدُۚ قُلۡ إِنَّمَا هُوَ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞ وَإِنَّنِي بَرِيٓءٞ مِّمَّا تُشۡرِكُونَ

Sọ pé: “Kí ni ohun tí ó tóbi jùlọ ní ẹ̀rí?” Sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin.” Ó sì fi ìmísí al-Ƙur’ān yìí ránṣẹ́ sí mi, nítorí kí n̄g lè fi ṣe ìkìlọ̀ fún ẹ̀yin àti ẹnikẹ́ni tí (al-Ƙur’ān) bá dé etí ìgbọ́ rẹ̀.[1] Ṣé dájúdájú ẹ̀yin ń jẹ́rìí pé àwọn ọlọ́hun mìíràn tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Sọ pé: “Èmi kò níí jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.” Sọ pé: “Òun nìkan ni Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Àti pé dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ (sí Allāhu).” info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūnus; 10:47.

التفاسير: