[1] Ìyẹn nígbà tí ọmọ òrukàn bá bàlágà, tí ó sì ní òye àmójútó dúkìá náà fúnra rẹ̀. [2] Bí àpẹ̀ẹrẹ, èyí ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí alágbàtọ́ ọmọ-òrukàn bá fi dúkìá kan tó dára nínú àwọn dúkìá ọmọ òrukàn pààrọ̀ dúkìá tirẹ̀ tí kò dára mọ́ ọn lọ́wọ́. Allāhu sì ṣe ìṣesí yìí ní èèwọ̀.
[1] Bí àpẹ̀ẹrẹ, kí ẹni tí ó ń mójútó ọmọ òrukàn obìnrin nífẹ̀ẹ́ láti fẹ́ ọmọbìnrin náà lẹ́yìn tí ó bàlágà tán, àmọ́ ọkùnrin náà kọ̀ láti fún un ní sọ̀daàkí rẹ̀ nítorí pé, ó mọ bí ogún ọmọbìnrin náà ṣe tó ní iye. [2]Láti ọ̀dọ̀ ọmọ Ṣihāb, dájúdájú ó gbọ́ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ fún ọkùnrin kan láti ìdìlé Thaƙīf tí ó gba ’Islām, tí ìyàwó rẹ̀ sì jẹ́ mẹ́wàá ní àsìkò tí ó gba ’Islām pé, “Mú mẹ́rin nínú wọn, kí o sì kọ àwọn yòókù sílẹ̀.” (Muwattọ’u Imām Mọ̄lik, Musnad Ṣāfi‘iy, Sunan Baehaƙiy àti Sọhīhu bn Hibbān)
[1] Ìyẹn ni pé, ẹ kọ́kọ́ fi díẹ̀ tó kéré gan-an lé e lọ́wọ́ nínú ogún rẹ̀ tó jẹ́ ohun àmúṣọrọ̀, kí ẹ wo bí ó ṣe máa ṣe àmójútó rẹ̀. [2] “eni tí ó lè ṣe ìgbéyàwó” ni ẹni tí ó ti di ọmọkùnrin tàbí ẹni tí ó ti di ọmọbìnrin ẹni tí “ó ti bàlágà”.