Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael

external-link copy
96 : 3

إِنَّ أَوَّلَ بَيۡتٖ وُضِعَ لِلنَّاسِ لَلَّذِي بِبَكَّةَ مُبَارَكٗا وَهُدٗى لِّلۡعَٰلَمِينَ

Dájúdájú ilé àkọ́kọ́ tí A fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn ni èyí tí ó wà ní Bakkah.[1] (Ó jẹ́ ilé) ìbùkún àti ìmọ̀nà fún gbogbo ẹ̀dá. info

[1] Bakkah jẹ́ orúkọ mìíràn fún Mọkkah. Ìtúmọ̀ Bakkah ni ìdìfúnǹfún. Ìdìfúnǹfún yìí kò sì lè má ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe tawāf lọ́wọ́ nínú Haram Mọkkah.

التفاسير: