1. Ní ìbẹ̀rẹ̀ hijrah ṣíṣe sọ ogún jíjẹ di ẹ̀tọ́ láti inú ẹbí kan fún ẹni tó ṣe hijrah. Àìṣe hijrah sì sọ ogún jíjẹ di èèwọ̀ láti inú ẹbí kan náà fún ẹni tí kò ṣe hijrah, wọn ìbáà dìjọ jẹ́ mùsùlùmí. Fífi hijrah sọ ogún jíjẹ di ẹ̀tọ́ sì wà bẹ́ẹ̀ títí wọ́n fi ṣí ìlú Mọkkah. Wọn kò si fi hijrah ṣíṣe pín ogún fún ẹnikẹ́ni mọ́ ní ìbámu sí āyah 75 nínú sūrah yìí. Lẹ́yìn náà, àwọn āyah ogún pípín fún àwọn ẹbí sọ̀kalẹ̀ nínú sūrah an-Nisā’.