1. Ní ìbámu sí āyah yìí, kí ẹnì kan ké odidi al-Ƙur’ān parí láààrin àsìkò díẹ̀ nípasẹ̀ ìkánjú kò lè mú kí onítọ̀ún gbádùn adùn al-Ƙur’ān. Kò sì lè mú ẹ̀san rẹ̀ kún kẹ́kẹ́.
1. Ìṣọ́-òru jẹ́ iṣẹ́ tí ẹ̀dá kò lágbára láti ṣe. Ìṣọ́-òru ni kí ẹ̀dá lérò pé òun kò níí fojú kan oorun láti alẹ́ mọ́júmọ́ lójojúmọ́.