Übersetzung der Bedeutungen von dem heiligen Quran - Die Übersetzung in Yoruba - Abu Rahimah Mikail

Nummer der Seite:close

external-link copy
11 : 24

إِنَّ ٱلَّذِينَ جَآءُو بِٱلۡإِفۡكِ عُصۡبَةٞ مِّنكُمۡۚ لَا تَحۡسَبُوهُ شَرّٗا لَّكُمۖ بَلۡ هُوَ خَيۡرٞ لَّكُمۡۚ لِكُلِّ ٱمۡرِيٕٖ مِّنۡهُم مَّا ٱكۡتَسَبَ مِنَ ٱلۡإِثۡمِۚ وَٱلَّذِي تَوَلَّىٰ كِبۡرَهُۥ مِنۡهُمۡ لَهُۥ عَذَابٌ عَظِيمٞ

Dájúdájú àwọn tó mú àdápa irọ́ wá jẹ́ ìjọ kan nínú yín. Ẹ má ṣe lérò pé aburú ni fún yín. Rárá o, oore ni fún yín. Ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ti ní ohun tí ó dá ní ẹ̀ṣẹ̀. Àti pé ẹni tí ó dá (ẹ̀ṣẹ̀) jùlọ nínú wọn, ìyà ńlá ni tirẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
12 : 24

لَّوۡلَآ إِذۡ سَمِعۡتُمُوهُ ظَنَّ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتُ بِأَنفُسِهِمۡ خَيۡرٗا وَقَالُواْ هَٰذَآ إِفۡكٞ مُّبِينٞ

Nígbà tí ẹ gbọ́ ọ, kí ni kò jẹ́ kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin ro dáadáa rora wọn, kí wọ́n sì sọ pé: “Èyí ni àdápa irọ́ pọ́nńbélé.” info
التفاسير:

external-link copy
13 : 24

لَّوۡلَا جَآءُو عَلَيۡهِ بِأَرۡبَعَةِ شُهَدَآءَۚ فَإِذۡ لَمۡ يَأۡتُواْ بِٱلشُّهَدَآءِ فَأُوْلَٰٓئِكَ عِندَ ٱللَّهِ هُمُ ٱلۡكَٰذِبُونَ

Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n mú ẹlẹ́rìí mẹ́rin wá lórí rẹ̀? Nítorí náà, nígbà tí wọn kò ti mú àwọn ẹlẹ́rìí wá, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni òpùrọ́ lọ́dọ̀ Allāhu. info
التفاسير:

external-link copy
14 : 24

وَلَوۡلَا فَضۡلُ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ وَرَحۡمَتُهُۥ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِ لَمَسَّكُمۡ فِي مَآ أَفَضۡتُمۡ فِيهِ عَذَابٌ عَظِيمٌ

Tí kì í bá ṣe ti oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ní ilé ayé àti ní ọ̀run ni, dájúdájú ìyà ńlá ìbá fọwọ́ bà yín nípa ohun tí ẹ̀ ń sọ kiri ní ìsọkúsọ. info
التفاسير:

external-link copy
15 : 24

إِذۡ تَلَقَّوۡنَهُۥ بِأَلۡسِنَتِكُمۡ وَتَقُولُونَ بِأَفۡوَاهِكُم مَّا لَيۡسَ لَكُم بِهِۦ عِلۡمٞ وَتَحۡسَبُونَهُۥ هَيِّنٗا وَهُوَ عِندَ ٱللَّهِ عَظِيمٞ

(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ̀ ń gbà á (láààrin ara yín) pẹ̀lú ahọ́n yín, tí ẹ sì ń fi ẹnu yín sọ ohun tí ẹ kò nímọ̀ nípa rẹ̀; ẹ lérò pé n̄ǹkan tó fúyẹ́ ni, n̄ǹkan ńlá sì ni lọ́dọ̀ Allāhu. info
التفاسير:

external-link copy
16 : 24

وَلَوۡلَآ إِذۡ سَمِعۡتُمُوهُ قُلۡتُم مَّا يَكُونُ لَنَآ أَن نَّتَكَلَّمَ بِهَٰذَا سُبۡحَٰنَكَ هَٰذَا بُهۡتَٰنٌ عَظِيمٞ

Nígbà tí ẹ gbọ́ ọ, kí ni kò jẹ́ kí ẹ sọ pé: “Kì í ṣe ẹ̀tọ́ fún wa pé kí á sọ èyí. Mímọ́ ni fún Ọ (Allāhu)! Èyí ni ìparọ́-mọ́ni tó tóbi.” info
التفاسير:

external-link copy
17 : 24

يَعِظُكُمُ ٱللَّهُ أَن تَعُودُواْ لِمِثۡلِهِۦٓ أَبَدًا إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ

Allāhu ń ṣe wáàsí fún yín pé kí ẹ má ṣe padà síbi irú rẹ̀ mọ́ láéláé tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
18 : 24

وَيُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمُ ٱلۡأٓيَٰتِۚ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ

Allāhu ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fún yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
19 : 24

إِنَّ ٱلَّذِينَ يُحِبُّونَ أَن تَشِيعَ ٱلۡفَٰحِشَةُ فِي ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِۚ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ وَأَنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ

Dájúdájú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí kí (ọ̀rọ̀) ìbàjẹ́ máa tàn kálẹ̀ nípa àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn ní ayé àti ní ọ̀run. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
20 : 24

وَلَوۡلَا فَضۡلُ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ وَرَحۡمَتُهُۥ وَأَنَّ ٱللَّهَ رَءُوفٞ رَّحِيمٞ

Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ni (Allāhu ìbá tètè fìyà jẹ yín ni). Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run. info
التفاسير: