[1] Suddiy àti Ƙọtādah túmọ̀ “’athā” sí “ìdọ̀tí”, Mujāhid túmọ̀ rẹ̀ sí “ẹ̀jẹ̀”. (Tọbariy). [2] عَنْ أَنَسٍ أَنَّ الْيَهُودَ كَانُوا إِذَا حَاضَتِ الْمَرْأَةُ فِيهِمْ لَمْ يُؤَاكِلُوهَا وَلَمْ يُجَامِعُوهُنَّ فِى الْبُيُوتِ فَسَأَلَ أَصْحَابُ النَّبِىِّ -صلى الله عليه وسلم- النَّبِىَّ -صلى الله عليه وسلم- فَأَنْزَلَ اللَّهُ تَعَالَى ( وَيَسْأَلُونَكَ عَنِ الْمَحِيضِ قُلْ هُوَ أَذًى فَاعْتَزِلُوا النِّسَاءَ فِى الْمَحِيضِ) إِلَى آخِرِ الآيَةِ فَقَالَ رَسُولُ اللَّهِ -صلى الله عليه وسلم- « اصْنَعُوا كُلَّ شَىْءٍ إِلاَّ النِّكَاحَ ». Láti ọ̀dọ̀ ’Anas - kí Allāhu yọ́nú sí i -, “Dájúdájú àwọn yẹ̀húdí, nígbàkígbà tí obìnrin kan nínú wọn bá ń ṣe héélà lọ́wọ́, wọn kò níí bá jẹun papọ̀, wọn kò níí súnmọ́ ọn nínú ilé. Àwọn Sọhābah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì bi Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - léèrè. Allāhu - tó ga jùlọ - sì sọ āyah yìí kalẹ̀. Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé, “Ẹ ṣe gbogbo n̄ǹkan àfi ìtìbọ̀.” Muslim ló gbà á wá. Ìyẹn ni pé, “Ẹ bá oníhéélà jẹun, ẹ bá a ṣeré, ẹ dìmọ́ ọn, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́dọ̀ ti kálámù bọ inú ìgò tàdáà àfi lẹ́yìn ìmọ́ra àti ìwẹ̀ ìmọ́ra.”