Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik - Ebu Rahime Mikail

Broj stranice:close

external-link copy
171 : 7

۞ وَإِذۡ نَتَقۡنَا ٱلۡجَبَلَ فَوۡقَهُمۡ كَأَنَّهُۥ ظُلَّةٞ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُۥ وَاقِعُۢ بِهِمۡ خُذُواْ مَآ ءَاتَيۡنَٰكُم بِقُوَّةٖ وَٱذۡكُرُواْ مَا فِيهِ لَعَلَّكُمۡ تَتَّقُونَ

(Rántí) nígbà tí A gbé àpáta ga sókè orí wọn, ó sì dà bí ibòji. Wọ́n sì lérò pé ó máa wó lu àwọn mọ́lẹ̀, (A sì sọ fún wọn pé): “Ẹ gbá ohun tí A fún yín mú dáadáa, kí ẹ sì máa rántí ohun tó ń bẹ nínú rẹ̀, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu).” info
التفاسير:

external-link copy
172 : 7

وَإِذۡ أَخَذَ رَبُّكَ مِنۢ بَنِيٓ ءَادَمَ مِن ظُهُورِهِمۡ ذُرِّيَّتَهُمۡ وَأَشۡهَدَهُمۡ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِمۡ أَلَسۡتُ بِرَبِّكُمۡۖ قَالُواْ بَلَىٰ شَهِدۡنَآۚ أَن تَقُولُواْ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ إِنَّا كُنَّا عَنۡ هَٰذَا غَٰفِلِينَ

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ādam nínú àrọ́mọdọ́mọ wọn tó fà jáde láti (ìbàdí ní) ẹ̀yìn (bàbá ńlá) wọn, Ó sì fi wọ́n ṣe ẹlẹ́rìí lórí ara wọn pé: “Ṣé Èmi kọ́ ni Olúwa yín ni?” Wọ́n sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni – (Ìwọ ni Olúwa wa) - a jẹ́rìí sí i.” Nítorí kí ẹ má baà sọ ní Ọjọ́ Àjíǹdé pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ aláìmọ̀ nípa èyí.” info
التفاسير:

external-link copy
173 : 7

أَوۡ تَقُولُوٓاْ إِنَّمَآ أَشۡرَكَ ءَابَآؤُنَا مِن قَبۡلُ وَكُنَّا ذُرِّيَّةٗ مِّنۢ بَعۡدِهِمۡۖ أَفَتُهۡلِكُنَا بِمَا فَعَلَ ٱلۡمُبۡطِلُونَ

Tàbí kí ẹ má baà wí pé: “Àwọn bàbá wa ló kúkú bá Allāhu wá akẹgbẹ́ ṣíwájú (wa), àwa sì jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ lẹ́yìn wọn (ni a fi wò wọ́n kọ́ṣe pẹ̀lú àìmọ̀kan). Ṣé Ìwọ yóò pa wá run nítorí ohun tí àwọn tó ń ba iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn jẹ́[1] ṣe ni?” info

1. Àwọn tó ń ba iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn jẹ́ ni àwọn ọ̀sẹbọ nítorí pé ẹbọ ṣíṣe máa ń ba iṣẹ́ ẹ̀dá jẹ́.

التفاسير:

external-link copy
174 : 7

وَكَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ وَلَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ

Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Wa, nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo). info
التفاسير:

external-link copy
175 : 7

وَٱتۡلُ عَلَيۡهِمۡ نَبَأَ ٱلَّذِيٓ ءَاتَيۡنَٰهُ ءَايَٰتِنَا فَٱنسَلَخَ مِنۡهَا فَأَتۡبَعَهُ ٱلشَّيۡطَٰنُ فَكَانَ مِنَ ٱلۡغَاوِينَ

Ka ìròyìn ẹni tí A fún ní àwọn āyah Wa fún wọn, tí ó yọra rẹ̀ sílẹ̀ níbi àwọn āyah náà.[1] Nítorí náà, aṣ-Ṣaetọ̄n tẹ̀lé e lẹ́yìn. Ó sì wà nínú àwọn olùṣìnà. info

1. Ó pa ìmọ̀ tì bí ìgbà tí ejò bá bọ́ ìhọ rẹ̀ sílẹ̀.

التفاسير:

external-link copy
176 : 7

وَلَوۡ شِئۡنَا لَرَفَعۡنَٰهُ بِهَا وَلَٰكِنَّهُۥٓ أَخۡلَدَ إِلَى ٱلۡأَرۡضِ وَٱتَّبَعَ هَوَىٰهُۚ فَمَثَلُهُۥ كَمَثَلِ ٱلۡكَلۡبِ إِن تَحۡمِلۡ عَلَيۡهِ يَلۡهَثۡ أَوۡ تَتۡرُكۡهُ يَلۡهَثۚ ذَّٰلِكَ مَثَلُ ٱلۡقَوۡمِ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَاۚ فَٱقۡصُصِ ٱلۡقَصَصَ لَعَلَّهُمۡ يَتَفَكَّرُونَ

Àti pé tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá fi (ìmọ̀ nípa àwọn āyah Wa) ṣàgbéga fún un. Ṣùgbọ́n ó wayé mọ́yà. Ó sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀. Nítorí náà, àfiwé rẹ̀ dà bí ajá. Tí o bá lé e síwájú, ó máa yọ ahọ́n síta. Tí o bá sì fi sílẹ̀, ó tún máa yọ ahọ́n síta. Ìyẹn ni àfiwé ìjọ tó pe àwọn āyah Wa nírọ́. Sọ ìtàn náà fún wọn nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
177 : 7

سَآءَ مَثَلًا ٱلۡقَوۡمُ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا وَأَنفُسَهُمۡ كَانُواْ يَظۡلِمُونَ

Ìjọ tí ó pe àwọn āyah Wa nírọ́, wọ́n burú ní àfiwé. Ara wọn sì ni wọ́n ń ṣàbòsí sí. info
التفاسير:

external-link copy
178 : 7

مَن يَهۡدِ ٱللَّهُ فَهُوَ ٱلۡمُهۡتَدِيۖ وَمَن يُضۡلِلۡ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ

Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), òun ni olùmọ̀nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá sì ṣì lọ́nà, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò. info
التفاسير: