1. “títí kò fi níí sí ogun ẹ̀sìn mọ́” Ìgbà wo ni ìyẹn máa ṣẹlẹ̀ nílé ayé? Mujāhid - kí Allāhu kẹ́ ẹ - sọ pé, “Títí di ìgbà tí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - yóò fi sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ ní òpin ayé.” Ìyẹn ni pé, ó di ìgbà tí Ànábì ‘Īsā bá tó sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ kí ogun ẹ̀sìn tó kásẹ̀ nílẹ̀.
1. Allāhu - Onímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba - ti fi Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀ mọ̀ wá pẹ̀lú oríkì kíkún àti àkàwé tó lágbára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ọkàn wa fi ń jẹ̀rankàn rẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣe àwọn iṣẹ́ tí Allāhu máa fi ṣíjú àánú Rẹ̀ wò wá ní ọjọ́ Àjíǹde.