1. Āyah yìí jẹ́ kò tako ìpadàbọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -, torí pé, ìpadàbọ̀ rẹ̀ ní òpin ayé ní àwọn ẹ̀rí tirẹ̀ lọ́tọ̀ nínú àwọn hadīth tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀.
1. Ìyẹn ni pé, ohunkóhun tí ó bá gbà ní ẹ̀san nílé ayé, òhun nìkan ni ẹ̀san ẹni tí ó bá fi ẹ̀sìn rẹ̀ wá oore ayé. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah al-Baƙọrah; 2:200.