Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik - Ebu Rahime Mikail

Yuunus

external-link copy
1 : 10

الٓرۚ تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡحَكِيمِ

’Alif Lām Rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tí ó kún fún ọgbọ́n.² info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1. 2.Pípe al-Ƙur’ān ní “hakīm” lè túmọ̀ sí n̄ǹkan mẹ́ta; tírà tí ó kún fún ọgbọ́n, tírà tí ó ń ṣe ìdájọ́ àti tírà tí wọ́n to àwọn āyah rẹ̀ àti sūrah rẹ̀ tó gún régé láì sí ìdàrúdàpọ̀ àti ìtakora kan nínú rẹ̀.

التفاسير:

external-link copy
2 : 10

أَكَانَ لِلنَّاسِ عَجَبًا أَنۡ أَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ رَجُلٖ مِّنۡهُمۡ أَنۡ أَنذِرِ ٱلنَّاسَ وَبَشِّرِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَنَّ لَهُمۡ قَدَمَ صِدۡقٍ عِندَ رَبِّهِمۡۗ قَالَ ٱلۡكَٰفِرُونَ إِنَّ هَٰذَا لَسَٰحِرٞ مُّبِينٌ

Ṣé ó jẹ́ kàyééfì fún àwọn ènìyàn pé A fi ìmísí ránṣẹ́ sí arákùnrin kan nínú wọn pé: “Ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kí o sì fún àwọn tó gbàgbọ́ ní ìró ìdùnnú pé ẹ̀san rere (iṣẹ́ tí wọ́n ṣe) ṣíwájú ti wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.”? Àwọn aláìgbàgbọ́ wí pé: “Dájúdájú òpìdán pọ́nńbélé mà ni (Ànábì) yìí.” info
التفاسير:

external-link copy
3 : 10

إِنَّ رَبَّكُمُ ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰ عَلَى ٱلۡعَرۡشِۖ يُدَبِّرُ ٱلۡأَمۡرَۖ مَا مِن شَفِيعٍ إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ إِذۡنِهِۦۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡ فَٱعۡبُدُوهُۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ

Dájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó ń ṣètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá). Kò sí olùṣìpẹ̀ kan àfi lẹ́yìn ìyọ̀ǹda Rẹ̀. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni? info
التفاسير:

external-link copy
4 : 10

إِلَيۡهِ مَرۡجِعُكُمۡ جَمِيعٗاۖ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقًّاۚ إِنَّهُۥ يَبۡدَؤُاْ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥ لِيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ بِٱلۡقِسۡطِۚ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَهُمۡ شَرَابٞ مِّنۡ حَمِيمٖ وَعَذَابٌ أَلِيمُۢ بِمَا كَانُواْ يَكۡفُرُونَ

Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ibùpadàsí gbogbo yín. (Ó jẹ́) àdéhùn Allāhu ní ti òdodo. Dájúdájú Òun l’Ó ń pilẹ̀ dídá ẹ̀dá. Lẹ́yìn náà, Ó máa da á padà (sọ́dọ̀ Rẹ̀) nítorí kí Ó lè fi déédé san ẹ̀san fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, ohun mímu tó gbóná parí àti ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn nítorí pé, wọ́n ṣàì gbàgbọ́. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 10

هُوَ ٱلَّذِي جَعَلَ ٱلشَّمۡسَ ضِيَآءٗ وَٱلۡقَمَرَ نُورٗا وَقَدَّرَهُۥ مَنَازِلَ لِتَعۡلَمُواْ عَدَدَ ٱلسِّنِينَ وَٱلۡحِسَابَۚ مَا خَلَقَ ٱللَّهُ ذَٰلِكَ إِلَّا بِٱلۡحَقِّۚ يُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٖ يَعۡلَمُونَ

(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òòrùn ní ìtànsán. (Ó ṣe) òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀. Ó sì díwọ̀n (ìrísí) rẹ̀ sínú àwọn ibùsọ̀ nítorí kí ẹ lè mọ òǹkà àwọn ọdún àti ìṣírò (ọjọ́). Allāhu kò dá ìyẹn bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Ó ń ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ tó nímọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 10

إِنَّ فِي ٱخۡتِلَٰفِ ٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ وَمَا خَلَقَ ٱللَّهُ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَتَّقُونَ

Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìtẹ̀léǹtẹ̀lé òru àti ọ̀sán àti ohun tí Allāhu dá sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; (àmì wà nínú wọn) fún ìjọ tó ń bẹ̀rù (Allāhu). info
التفاسير: