ٱسۡتَغۡفِرۡ لَهُمۡ أَوۡ لَا تَسۡتَغۡفِرۡ لَهُمۡ إِن تَسۡتَغۡفِرۡ لَهُمۡ سَبۡعِينَ مَرَّةٗ فَلَن يَغۡفِرَ ٱللَّهُ لَهُمۡۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَفَرُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦۗ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡفَٰسِقِينَ
Yálà o tọrọ àforíjìn fún wọ́n tàbí o ò tọrọ àforíjìn fún wọn - kódà kí o tọrọ àforíjìn fún wọn nígbà ààdọ́rin - Allāhu kò níí foríjìn wọ́n.[1] Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjísẹ́ Rẹ̀. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
1. Ìyẹn nípa ti àwọn munāfiki, kì í ṣe nípa ti àwọn mùsùlùmí onígbàgbọ́ òdodo.
التفاسير: