1. Ìyẹn ni pé, ẹ jẹ́ kí wọ́n ṣe “‘iddatu-ttọlāƙ” (opó ìkọ̀sílẹ̀) parí kí yìgì ààrin yín tó ó já. Lẹ́yìn náà, kí ó padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀. Bákan náà, a kì í sọ pé “mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀” ní àsìkò tí obìnrin bá ń ṣe héélà rẹ̀ lọ́wọ́ tàbí lẹ́yìn ìbálòpọ̀ tó wáyé lẹ́yìn ìmọ́ra níbi héélà.
1. Ìyẹn ni pé, ẹ lè dá gbólóhùn ìkọ̀sílẹ̀ pada (ìyẹn tí ìkọ̀sílẹ̀ kò bá tí ì pé ìgbà mẹ́ta) tàbí ẹ sì lè takú sórí gbólóhùn ìkọ̀sílẹ̀ náà títí òǹkà n̄ǹkan oṣù mẹ́ta yóò fi ko sẹ̀.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mujādilah 58:7.