Ṣé wọn kò wòye pé ó pọ̀ nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn? Àwọn tí A fún ní ipò lórí ilẹ̀, (irú) ipò tí A kò fún ẹ̀yin. A sì rọ omi òjò púpọ̀ fún wọn láti sánmọ̀. A sì ṣe àwọn odò tí ń ṣàn sí ìsàlẹ̀ (ilé) wọn. Lẹ́yìn náà, A pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. A sì dá àwọn ìran mìíràn lẹ́yìn wọn.
Tí ó bá jẹ́ pé A sọ tírà kan tí A kọ sínú tákàdá kalẹ̀ fún ọ, kí wọ́n sì fi ọwọ́ ara wọn gbá a mú (báyìí), dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ìbá wí pé: “Èyí kò jẹ́ n̄ǹkan kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”
Wọ́n sì wí pé: “Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún un?” Tí ó bá jẹ́ pé A sọ mọlāika kan kalẹ̀, ọ̀rọ̀ ìbá ti yanjú. Lẹ́yìn náà, A ò sì níí lọ́ wọn lára mọ́.