ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - أبو رحيمة ميكائيل

external-link copy
15 : 4

وَٱلَّٰتِي يَأۡتِينَ ٱلۡفَٰحِشَةَ مِن نِّسَآئِكُمۡ فَٱسۡتَشۡهِدُواْ عَلَيۡهِنَّ أَرۡبَعَةٗ مِّنكُمۡۖ فَإِن شَهِدُواْ فَأَمۡسِكُوهُنَّ فِي ٱلۡبُيُوتِ حَتَّىٰ يَتَوَفَّىٰهُنَّ ٱلۡمَوۡتُ أَوۡ يَجۡعَلَ ٱللَّهُ لَهُنَّ سَبِيلٗا

Àwọn tó ń ṣe sìná nínú àwọn obìnrin yín, ẹ wá ẹlẹ́rìí mẹ́rin nínú yín tí ó máa jẹ́rìí lé wọn lórí. Tí wọ́n bá jẹ́rìí lé wọn lórí, kí ẹ dè wọ́n mọ́ inú ilé títí ikú yóò fi pa wọ́n tàbí (títí) Allāhu yóò fi gbé ọ̀nà (ìjìyà) kan kalẹ̀ fún wọn.[1] info

1. Èyí ni òfin àkọ́kọ́ lórí ìdíyàjẹ onísìná obìnrin tó ti ní yìgì lórí rí. Lẹ́yìn náà, òfin lílẹ onísìná lókò pa dé lórí ẹni tí ó bá ṣe sìná lẹ́yìn tí ó ti ṣe nikāh rí, yálà obìnrin tàbí ọkùnrin.

التفاسير: