ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - أبو رحيمة ميكائيل

رقم الصفحة:close

external-link copy
163 : 4

۞ إِنَّآ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ كَمَآ أَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ نُوحٖ وَٱلنَّبِيِّـۧنَ مِنۢ بَعۡدِهِۦۚ وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰٓ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡمَٰعِيلَ وَإِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَ وَٱلۡأَسۡبَاطِ وَعِيسَىٰ وَأَيُّوبَ وَيُونُسَ وَهَٰرُونَ وَسُلَيۡمَٰنَۚ وَءَاتَيۡنَا دَاوُۥدَ زَبُورٗا

Dájúdájú Àwa (fi ìmísí) ránṣẹ́ sí ọ gẹ́gẹ́ bí A ṣe fi ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh àti àwọn Ànábì (mìíràn) lẹ́yìn rẹ̀. A fi ìmísí ránṣẹ́ sí (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀), àti (Ànábì) ‘Īsā, ’Ayyūb, Yūnus, Hārūn àti Sulaemọ̄n. A sì fún (Ànábì) Dāwūd ní Zabūr. info
التفاسير:

external-link copy
164 : 4

وَرُسُلٗا قَدۡ قَصَصۡنَٰهُمۡ عَلَيۡكَ مِن قَبۡلُ وَرُسُلٗا لَّمۡ نَقۡصُصۡهُمۡ عَلَيۡكَۚ وَكَلَّمَ ٱللَّهُ مُوسَىٰ تَكۡلِيمٗا

Àti àwọn Òjíṣẹ́ kan tí A ti sọ ìtàn wọn fún ọ ṣíwájú pẹ̀lú àwọn Òjíṣẹ́ kan tí A kò sọ ìtàn wọn fún ọ. Allāhu sì bá (Ànábì) Mūsā sọ̀rọ̀ tààrà. info
التفاسير:

external-link copy
165 : 4

رُّسُلٗا مُّبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ لِئَلَّا يَكُونَ لِلنَّاسِ عَلَى ٱللَّهِ حُجَّةُۢ بَعۡدَ ٱلرُّسُلِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمٗا

(A ṣe wọ́n ní) Òjíṣẹ́, oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀ nítorí kí àwíjàre má lè wà fún àwọn ènìyàn lọ́dọ̀ Allāhu lẹ́yìn (tí) àwọn Òjíṣẹ́ (ti jíṣẹ́). Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
166 : 4

لَّٰكِنِ ٱللَّهُ يَشۡهَدُ بِمَآ أَنزَلَ إِلَيۡكَۖ أَنزَلَهُۥ بِعِلۡمِهِۦۖ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ يَشۡهَدُونَۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدًا

Ṣùgbọ́n Allāhu ń jẹ́rìí sí ohun tí Ó sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. Àwọn mọlāika náà ń jẹ́rìí (sí i). Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí. info
التفاسير:

external-link copy
167 : 4

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَصَدُّواْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ قَدۡ ضَلُّواْ ضَلَٰلَۢا بَعِيدًا

Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, wọ́n kúkú ti ṣìnà ní ìṣìnà tó jìnnà. info
التفاسير:

external-link copy
168 : 4

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَظَلَمُواْ لَمۡ يَكُنِ ٱللَّهُ لِيَغۡفِرَ لَهُمۡ وَلَا لِيَهۡدِيَهُمۡ طَرِيقًا

Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún ṣàbòsí, Allāhu kò níí forí jìn wọ́n, kò sì níí fi ojú-ọ̀nà kan mọ̀ wọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
169 : 4

إِلَّا طَرِيقَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدٗاۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٗا

Àyàfi ojú-ọ̀nà iná Jahanamọ. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Ìyẹn sì ń jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu.[1] info

1. Èyí wà fún ẹni tí ó bá kú sínú àìgbàgbọ́ lẹ́yìn tí ìkéde ẹ̀sìn ’Islām ti dé etí ìgbọ́ rẹ̀. Bákan náà, ẹ wo āyah 48 àti āyah 116.

التفاسير:

external-link copy
170 : 4

يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ قَدۡ جَآءَكُمُ ٱلرَّسُولُ بِٱلۡحَقِّ مِن رَّبِّكُمۡ فَـَٔامِنُواْ خَيۡرٗا لَّكُمۡۚ وَإِن تَكۡفُرُواْ فَإِنَّ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمٗا

Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Òjíṣẹ́ náà ti dé ba yín pẹ̀lú òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, kí ẹ gbà á gbọ́ l’ó dára jùlọ fún yín. Tí ẹ bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. info
التفاسير: