ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - أبو رحيمة ميكائيل

سورة الصافات - As-Sooffaat

external-link copy
1 : 37

وَٱلصَّٰٓفَّٰتِ صَفّٗا

Allāhu fi àwọn mọlāika tí ó ń tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ búra. info
التفاسير:

external-link copy
2 : 37

فَٱلزَّٰجِرَٰتِ زَجۡرٗا

Allāhu tún fi àwọn mọlāika tó ń wọ́ ẹ̀ṣújò kiri tààrà bura. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 37

فَٱلتَّٰلِيَٰتِ ذِكۡرًا

Allāhu tún fi àwọn mọlāika tó ń ka ìrántí bura. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 37

إِنَّ إِلَٰهَكُمۡ لَوَٰحِدٞ

Dájúdájú ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 37

رَّبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا وَرَبُّ ٱلۡمَشَٰرِقِ

Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Òun sì ni Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 37

إِنَّا زَيَّنَّا ٱلسَّمَآءَ ٱلدُّنۡيَا بِزِينَةٍ ٱلۡكَوَاكِبِ

Dájúdájú Àwa fi àwọn ìràwọ̀ ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́ info
التفاسير:

external-link copy
7 : 37

وَحِفۡظٗا مِّن كُلِّ شَيۡطَٰنٖ مَّارِدٖ

àti ìṣọ́ kúrò níbi (aburú) gbogbo aṣ-Ṣaetọ̄n olóríkunkun. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 37

لَّا يَسَّمَّعُونَ إِلَى ٱلۡمَلَإِ ٱلۡأَعۡلَىٰ وَيُقۡذَفُونَ مِن كُلِّ جَانِبٖ

(Àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n) kò sì níí lè tẹ́tí sí ìjọ (mọlāika tó wà ní) àyè gíga jùlọ (nínú sánmọ̀. Bí wọ́n bá sì gbìyànjú láti yọ́ ọ̀rọ̀ gbọ́ láti sánmọ̀, àwọn mọlāika) yó sì máa kù wọ́n lókò (ẹ̀ta ìràwọ̀) ní gbogbo agbègbè (sánmọ̀). info
التفاسير:

external-link copy
9 : 37

دُحُورٗاۖ وَلَهُمۡ عَذَابٞ وَاصِبٌ

Wọ́n máa lé wọn dànù. Ìyà àìlópin sì wà fún wọn. info
التفاسير:

external-link copy
10 : 37

إِلَّا مَنۡ خَطِفَ ٱلۡخَطۡفَةَ فَأَتۡبَعَهُۥ شِهَابٞ ثَاقِبٞ

(Wọn kò níí gbọ́ ọ̀rọ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́) àyàfi ẹni tí ó bá rí ọ̀rọ̀ àjígbọ́ gbé, nígbà náà (ni mọlāika) yó sì fi ẹ̀ta ìràwọ̀ iná tó máa jó o tẹ̀lé e.[1] info

1. Àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n àlùjànnú máa ń gbé ara wọn gunra wọn láti lè súnmọ́ etí sánmọ̀ ilé ayé. Bí wọ́n bá bá àwọn mọlāika lórí àwọn ìro kan tí Allāhu fi ránṣẹ́ sí wọn, wọ́n máa jí i gbọ́.

التفاسير:

external-link copy
11 : 37

فَٱسۡتَفۡتِهِمۡ أَهُمۡ أَشَدُّ خَلۡقًا أَم مَّنۡ خَلَقۡنَآۚ إِنَّا خَلَقۡنَٰهُم مِّن طِينٖ لَّازِبِۭ

Bi wọ́n léèrè wò pé, ṣé àwọn (ènìyàn) ni ìṣẹ̀dá wọn lágbára jùlọ ni tàbí àwọn (n̄ǹkan mìíràn)[1] tí A dá? Dájúdájú Àwa dá àwọn (ènìyàn) láti ara ẹrẹ̀ tó lẹ̀ mọ́ra wọn. info

1. Àwọn n̄ǹkan mìíràn bíi àwọn sánmọ̀, àwọn ilẹ̀, àwọn mọlāika àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

التفاسير:

external-link copy
12 : 37

بَلۡ عَجِبۡتَ وَيَسۡخَرُونَ

Rárá (kò jọra wọn); ìwọ ṣèèmọ̀ (nípa al-Ƙur’ān), àwọn sì ń ṣe yẹ̀yẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
13 : 37

وَإِذَا ذُكِّرُواْ لَا يَذۡكُرُونَ

Àti pé nígbà tí wọ́n bá ṣe ìrántí fún wọn, wọn kò níí lo ìrántí. info
التفاسير:

external-link copy
14 : 37

وَإِذَا رَأَوۡاْ ءَايَةٗ يَسۡتَسۡخِرُونَ

Nígbà tí wọ́n bá tún rí àmì kan, wọn yóò máa ṣe yẹ̀yẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
15 : 37

وَقَالُوٓاْ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٞ مُّبِينٌ

Wọ́n sì wí pé: “Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé. info
التفاسير:

external-link copy
16 : 37

أَءِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابٗا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَبۡعُوثُونَ

Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò tún gbé wa dìde ni? info
التفاسير:

external-link copy
17 : 37

أَوَءَابَآؤُنَا ٱلۡأَوَّلُونَ

Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?” info
التفاسير:

external-link copy
18 : 37

قُلۡ نَعَمۡ وَأَنتُمۡ دَٰخِرُونَ

Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀yin yó sì di ẹni yẹpẹrẹ.” info
التفاسير:

external-link copy
19 : 37

فَإِنَّمَا هِيَ زَجۡرَةٞ وَٰحِدَةٞ فَإِذَا هُمۡ يَنظُرُونَ

Nítorí náà, igbe ẹyọ kan mà ni. Nígbà náà ni wọn yóò máa wò sùn. info
التفاسير:

external-link copy
20 : 37

وَقَالُواْ يَٰوَيۡلَنَا هَٰذَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ

Wọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò! Èyí ni Ọjọ́ ẹ̀san.” info
التفاسير:

external-link copy
21 : 37

هَٰذَا يَوۡمُ ٱلۡفَصۡلِ ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ

Èyí ni ọjọ́ Ìdájọ́ èyí tí ẹ̀ ń pè ní irọ́. info
التفاسير:

external-link copy
22 : 37

۞ ٱحۡشُرُواْ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ وَأَزۡوَٰجَهُمۡ وَمَا كَانُواْ يَعۡبُدُونَ

Ẹ kó àwọn tó ṣàbòsí jọ, àwọn ìyàwó wọn àti ohun tí wọ́n ń jọ́sìn fún info
التفاسير:

external-link copy
23 : 37

مِن دُونِ ٱللَّهِ فَٱهۡدُوهُمۡ إِلَىٰ صِرَٰطِ ٱلۡجَحِيمِ

lẹ́yìn Allāhu. Kí ẹ sì júwe wọn sí ojú ọ̀nà iná Jẹhīm. info
التفاسير:

external-link copy
24 : 37

وَقِفُوهُمۡۖ إِنَّهُم مَّسۡـُٔولُونَ

Ẹ dá wọn dúró ná, dájúdájú wọ́n máa bi wọ́n léèrè ìbéèrè. info
التفاسير: