《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译 - 艾布·拉西麦·米卡依赖。

Adh-Dhaariyat

external-link copy
1 : 51

وَٱلذَّٰرِيَٰتِ ذَرۡوٗا

Allāhu fi atẹ́gùn tó ń tu erùpẹ̀ jáde nílẹ̀ ní títu-jáde tààrà búra. info
التفاسير:

external-link copy
2 : 51

فَٱلۡحَٰمِلَٰتِ وِقۡرٗا

Allāhu fi àwọn ẹ̀ṣújò tó ru òjò tó wúwo búra. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 51

فَٱلۡجَٰرِيَٰتِ يُسۡرٗا

Allāhu fi àwọn ọkọ̀ ojú-omi tó ń rìn pẹ̀lú ìrọ̀rùn búra. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 51

فَٱلۡمُقَسِّمَٰتِ أَمۡرًا

Allāhu fi àwọn mọlāika tó ń pín n̄ǹkan tí Ó ti pín fún ẹ̀dá búra. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 51

إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَصَادِقٞ

Òdodo mà ni ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 51

وَإِنَّ ٱلدِّينَ لَوَٰقِعٞ

Àti pé dájúdájú ẹ̀san iṣẹ́ máa ṣẹlẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 51

وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلۡحُبُكِ

Allāhu tún fi sánmọ̀ ọlọ́ṣọ̀ọ́ tó gún régé búra. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 51

إِنَّكُمۡ لَفِي قَوۡلٖ مُّخۡتَلِفٖ

Dájúdájú ẹ̀yin wà lórí ọ̀rọ̀ tó ń takora wọn (nípa al-Ƙur’ān). info
التفاسير:

external-link copy
9 : 51

يُؤۡفَكُ عَنۡهُ مَنۡ أُفِكَ

Ẹni tí wọ́n ń ṣẹ́ lórí kúrò níbi al-Ƙur’ān ni ẹni tí Wọ́n ti ṣẹ́ lórí kúrò níbẹ̀ (láti inú Laohul-Mahfūṭḥ). info
التفاسير:

external-link copy
10 : 51

قُتِلَ ٱلۡخَرَّٰصُونَ

Ègbé ni fún àwọn òpùrọ́; info
التفاسير:

external-link copy
11 : 51

ٱلَّذِينَ هُمۡ فِي غَمۡرَةٖ سَاهُونَ

àwọn tí wọ́n wà nínú àìmọ̀kan tó gbópọn tí wọ́n ti gbàgbéra. info
التفاسير:

external-link copy
12 : 51

يَسۡـَٔلُونَ أَيَّانَ يَوۡمُ ٱلدِّينِ

tí wọ́n ń bèèrè ìgbà tí Ọjọ́ Ẹ̀san máa ṣẹlẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
13 : 51

يَوۡمَ هُمۡ عَلَى ٱلنَّارِ يُفۡتَنُونَ

Ní ọjọ́ náà sì ni wọn yóò máa fi Iná jẹ wọ́n níyà. info
التفاسير:

external-link copy
14 : 51

ذُوقُواْ فِتۡنَتَكُمۡ هَٰذَا ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تَسۡتَعۡجِلُونَ

Ẹ tọ́ ìyà yín wò. Èyí ni n̄ǹkan tí ẹ ti ń wá pẹ̀lú ìkánjú. info
التفاسير:

external-link copy
15 : 51

إِنَّ ٱلۡمُتَّقِينَ فِي جَنَّٰتٖ وَعُيُونٍ

Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi odò ìṣẹ́lẹ̀rú (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀). info
التفاسير:

external-link copy
16 : 51

ءَاخِذِينَ مَآ ءَاتَىٰهُمۡ رَبُّهُمۡۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَبۡلَ ذَٰلِكَ مُحۡسِنِينَ

Wọn yóò máa gba n̄ǹkan tí Olúwa wọn bá fún wọn. Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ olùṣe-rere ṣíwájú ìyẹn. info
التفاسير:

external-link copy
17 : 51

كَانُواْ قَلِيلٗا مِّنَ ٱلَّيۡلِ مَا يَهۡجَعُونَ

Wọ́n máa ń sun oorun díẹ̀ nínú òru. info
التفاسير:

external-link copy
18 : 51

وَبِٱلۡأَسۡحَارِ هُمۡ يَسۡتَغۡفِرُونَ

Wọ́n máa ń tọrọ àforíjìn ní àfẹ̀mọ́júmọ́. info
التفاسير:

external-link copy
19 : 51

وَفِيٓ أَمۡوَٰلِهِمۡ حَقّٞ لِّلسَّآئِلِ وَٱلۡمَحۡرُومِ

Nínú dúkìá wọn, wọ́n ní ojúṣe tí wọ́n ń ṣe fún alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún. info
التفاسير:

external-link copy
20 : 51

وَفِي ٱلۡأَرۡضِ ءَايَٰتٞ لِّلۡمُوقِنِينَ

Àwọn àmì wà ní orí ilẹ̀ fún àwọn alámọ̀dájú. info
التفاسير:

external-link copy
21 : 51

وَفِيٓ أَنفُسِكُمۡۚ أَفَلَا تُبۡصِرُونَ

Nínú ẹ̀mí ara yín gan-an (àmì ìyanu wà nínú rẹ̀). Ṣé ẹ kò ríran ni? info
التفاسير:

external-link copy
22 : 51

وَفِي ٱلسَّمَآءِ رِزۡقُكُمۡ وَمَا تُوعَدُونَ

Arísìkí yín àti ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín wà nínú sánmọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
23 : 51

فَوَرَبِّ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِ إِنَّهُۥ لَحَقّٞ مِّثۡلَ مَآ أَنَّكُمۡ تَنطِقُونَ

Nítorí náà, Mó fi Olúwa sánmọ̀ àti ilẹ̀ búra, dájúdájú òdodo ni (ọ̀rọ̀ náà) gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ òdodo pé ẹ̀ ń fẹnu sọ̀rọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
24 : 51

هَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ ضَيۡفِ إِبۡرَٰهِيمَ ٱلۡمُكۡرَمِينَ

Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn àlejò (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, ti dé ọ̀dọ̀ rẹ? info
التفاسير:

external-link copy
25 : 51

إِذۡ دَخَلُواْ عَلَيۡهِ فَقَالُواْ سَلَٰمٗاۖ قَالَ سَلَٰمٞ قَوۡمٞ مُّنكَرُونَ

(Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì sọ pé: “Àlàáfíà (fún ọ).” Òun náà sọ pé: “Àlàáfíà (fún yín), ẹ̀yin àjòjì ènìyàn.” info
التفاسير:

external-link copy
26 : 51

فَرَاغَ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦ فَجَآءَ بِعِجۡلٖ سَمِينٖ

Ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, ó sì dé pẹ̀lú ọmọ màálù tó ní ọ̀rá (tí wọ́n ti yangbẹ). info
التفاسير:

external-link copy
27 : 51

فَقَرَّبَهُۥٓ إِلَيۡهِمۡ قَالَ أَلَا تَأۡكُلُونَ

Ó gbé e súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn. Ó sì sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí jẹun ni?” info
التفاسير:

external-link copy
28 : 51

فَأَوۡجَسَ مِنۡهُمۡ خِيفَةٗۖ قَالُواْ لَا تَخَفۡۖ وَبَشَّرُوهُ بِغُلَٰمٍ عَلِيمٖ

Nígbà náà, ìbẹ̀rù wọn sì mú un.[1]. Wọ́n sọ pé: “Má ṣe páyà.” Wọ́n sì fún un ní ìró ìdùnnú nípa bíbí ọmọkùnrin kan tí ó máa ní ìmọ̀. info

1. Tàbí “ó pa ìbẹ̀rù wọn mọ́ra”.

التفاسير:

external-link copy
29 : 51

فَأَقۡبَلَتِ ٱمۡرَأَتُهُۥ فِي صَرَّةٖ فَصَكَّتۡ وَجۡهَهَا وَقَالَتۡ عَجُوزٌ عَقِيمٞ

Nígbà náà, ìyàwó rẹ̀ wọlé pẹ̀lú igbe, ó sì gbára rẹ̀ lójú, ó sọ pé: “Arúgbó, àgàn (mà ni mí)!” info
التفاسير:

external-link copy
30 : 51

قَالُواْ كَذَٰلِكِ قَالَ رَبُّكِۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡحَكِيمُ ٱلۡعَلِيمُ

Wọ́n sọ pé: “Báyẹn ni Olúwa rẹ sọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.” info
التفاسير:

external-link copy
31 : 51

۞ قَالَ فَمَا خَطۡبُكُمۡ أَيُّهَا ٱلۡمُرۡسَلُونَ

(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́?” info
التفاسير:

external-link copy
32 : 51

قَالُوٓاْ إِنَّآ أُرۡسِلۡنَآ إِلَىٰ قَوۡمٖ مُّجۡرِمِينَ

Wọ́n sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni info
التفاسير:

external-link copy
33 : 51

لِنُرۡسِلَ عَلَيۡهِمۡ حِجَارَةٗ مِّن طِينٖ

nítorí kí á lè fi òkúta amọ̀ (sísun) ránṣẹ́ sí wọn. info
التفاسير:

external-link copy
34 : 51

مُّسَوَّمَةً عِندَ رَبِّكَ لِلۡمُسۡرِفِينَ

Wọ́n ti fi àmì sí i lára lọ́dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn alákọyọ.” info
التفاسير:

external-link copy
35 : 51

فَأَخۡرَجۡنَا مَن كَانَ فِيهَا مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Nítorí náà, A mú àwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo jáde kúrò nínú (ìlú náà). info
التفاسير:

external-link copy
36 : 51

فَمَا وَجَدۡنَا فِيهَا غَيۡرَ بَيۡتٖ مِّنَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ

A kò sì rí nínú (ìlú náà) yàtọ̀ sí ilé kan tó jẹ́ ti àwọn mùsùlùmí. info
التفاسير:

external-link copy
37 : 51

وَتَرَكۡنَا فِيهَآ ءَايَةٗ لِّلَّذِينَ يَخَافُونَ ٱلۡعَذَابَ ٱلۡأَلِيمَ

A sì fi àmì kan sílẹ̀ nínú (ìlú náà) fún àwọn tó ń páyà ìyà ẹlẹ́ta-eléro. info
التفاسير:

external-link copy
38 : 51

وَفِي مُوسَىٰٓ إِذۡ أَرۡسَلۡنَٰهُ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ بِسُلۡطَٰنٖ مُّبِينٖ

(Àmì tún wà) lára (Ànábì) Mūsā. Nígbà tí A fi ẹ̀rí pọ́nńbélé rán an níṣẹ́ sí Fir‘aon. info
التفاسير:

external-link copy
39 : 51

فَتَوَلَّىٰ بِرُكۡنِهِۦ وَقَالَ سَٰحِرٌ أَوۡ مَجۡنُونٞ

Ṣùgbọ́n ó lo gbogbo agbára rẹ̀ láti kẹ̀yìn sí òdodo. Ó sì wí pé: “Òpìdán tàbí wèrè kan (nìyí).” info
التفاسير:

external-link copy
40 : 51

فَأَخَذۡنَٰهُ وَجُنُودَهُۥ فَنَبَذۡنَٰهُمۡ فِي ٱلۡيَمِّ وَهُوَ مُلِيمٞ

Nítorí náà, A mú òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀. A sì jù wọ́n sínú agbami odò nígbà tí ó jẹ́ alábùkù. info
التفاسير:

external-link copy
41 : 51

وَفِي عَادٍ إِذۡ أَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمُ ٱلرِّيحَ ٱلۡعَقِيمَ

(Àmì tún wà) lára ìjọ ‘Ād. (Rántí) nígbà tí A rán atẹ́gùn ìparun sí wọn. info
التفاسير:

external-link copy
42 : 51

مَا تَذَرُ مِن شَيۡءٍ أَتَتۡ عَلَيۡهِ إِلَّا جَعَلَتۡهُ كَٱلرَّمِيمِ

Kò fi kiní kan tó fẹ́ sí lára sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ àfi kí ó sọ ọ́ di n̄ǹkan tó kẹfun.[1] info

1. “n̄ǹkan tó kẹfun” ni n̄ǹkan tí ó ti gbó mọ́lẹ̀ tayọ dídámọ̀.

التفاسير:

external-link copy
43 : 51

وَفِي ثَمُودَ إِذۡ قِيلَ لَهُمۡ تَمَتَّعُواْ حَتَّىٰ حِينٖ

(Àmì tún wà) lára ìjọ Thamūd. (Rántí) nígbà tí A sọ fún wọn pé: “Ẹ jayé fún ìgbà díẹ̀ ná.” info
التفاسير:

external-link copy
44 : 51

فَعَتَوۡاْ عَنۡ أَمۡرِ رَبِّهِمۡ فَأَخَذَتۡهُمُ ٱلصَّٰعِقَةُ وَهُمۡ يَنظُرُونَ

Wọ́n ṣègbéraga sí àṣẹ Olúwa wọn. Nítorí náà, iná láti ojú sánmọ̀ gbá wọn mú; wọ́n sì ń wò bọ̀ọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
45 : 51

فَمَا ٱسۡتَطَٰعُواْ مِن قِيَامٖ وَمَا كَانُواْ مُنتَصِرِينَ

Wọn kò lè dìde nàró. Wọn kò sì lè ran ara wọn lọ́wọ́. info
التفاسير:

external-link copy
46 : 51

وَقَوۡمَ نُوحٖ مِّن قَبۡلُۖ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمٗا فَٰسِقِينَ

Àti ìjọ Nūh tí ó ṣíwájú (wọn), dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ arúfin. info
التفاسير:

external-link copy
47 : 51

وَٱلسَّمَآءَ بَنَيۡنَٰهَا بِأَيۡيْدٖ وَإِنَّا لَمُوسِعُونَ

Àti pé sánmọ̀, A mọ ọ́n (sí òkè yín) pẹ̀lú agbára. Dájúdájú Àwa sì ni Alágbára (tí a mú un tóbi). info
التفاسير:

external-link copy
48 : 51

وَٱلۡأَرۡضَ فَرَشۡنَٰهَا فَنِعۡمَ ٱلۡمَٰهِدُونَ

Àti ilẹ̀, A ṣe é ní ìtẹ́. (Àwa sì ni) olùtẹ́-ilẹ̀ sílẹ̀ tó dára. info
التفاسير:

external-link copy
49 : 51

وَمِن كُلِّ شَيۡءٍ خَلَقۡنَا زَوۡجَيۡنِ لَعَلَّكُمۡ تَذَكَّرُونَ

Àti pé gbogbo n̄ǹkan ni A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní oríṣi méjì-méjì nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yāsīn; 36:36.

التفاسير:

external-link copy
50 : 51

فَفِرُّوٓاْ إِلَى ٱللَّهِۖ إِنِّي لَكُم مِّنۡهُ نَذِيرٞ مُّبِينٞ

Nítorí náà, ẹ sá lọ sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
51 : 51

وَلَا تَجۡعَلُواْ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَۖ إِنِّي لَكُم مِّنۡهُ نَذِيرٞ مُّبِينٞ

Ẹ má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
52 : 51

كَذَٰلِكَ مَآ أَتَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا قَالُواْ سَاحِرٌ أَوۡ مَجۡنُونٌ

Báyẹn ni (ọ̀rọ̀ ṣe rí)! Òjíṣẹ́ kan kò wá bá àwọn tó ṣíwájú wọn àfi kí wọ́n wí pé: “Òpìdán tàbí wèrè ni.” info
التفاسير:

external-link copy
53 : 51

أَتَوَاصَوۡاْ بِهِۦۚ بَلۡ هُمۡ قَوۡمٞ طَاغُونَ

Ṣé wọn sọ àsọọ́lẹ̀ nípa rẹ̀ láààrin ara wọn ni? Rárá o! Ìjọ olùtayọ-ẹnu-ààlà ni wọ́n ni. info
التفاسير:

external-link copy
54 : 51

فَتَوَلَّ عَنۡهُمۡ فَمَآ أَنتَ بِمَلُومٖ

Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn ná. Ìwọ kì í ṣe ẹni tí A máa bá wí. info
التفاسير:

external-link copy
55 : 51

وَذَكِّرۡ فَإِنَّ ٱلذِّكۡرَىٰ تَنفَعُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Ṣèrántí nítorí pé, dájúdájú ìrántí máa wúlò fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
56 : 51

وَمَا خَلَقۡتُ ٱلۡجِنَّ وَٱلۡإِنسَ إِلَّا لِيَعۡبُدُونِ

Àti pé Èmi kò ṣẹ̀dá àlùjànnú àti ènìyàn bí kò ṣe pé kí wọ́n lè jọ́sìn fún Mi. info
التفاسير:

external-link copy
57 : 51

مَآ أُرِيدُ مِنۡهُم مِّن رِّزۡقٖ وَمَآ أُرِيدُ أَن يُطۡعِمُونِ

Èmi kò gbèrò arísìkí kan láti ọ̀dọ̀ wọn. Èmi kò sì gbèrò pé kí wọ́n máa bọ́ Mi. info
التفاسير:

external-link copy
58 : 51

إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلرَّزَّاقُ ذُو ٱلۡقُوَّةِ ٱلۡمَتِينُ

Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùpèsè, Alágbára líle. info
التفاسير:

external-link copy
59 : 51

فَإِنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُواْ ذَنُوبٗا مِّثۡلَ ذَنُوبِ أَصۡحَٰبِهِمۡ فَلَا يَسۡتَعۡجِلُونِ

Dájúdájú ìpín ìyà tí ó máa jẹ àwọn tó ṣàbòsí (wọ̀nyí) ni irú ìpín ìyà tí ó jẹ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ (irú) wọn. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe kán Mi lójú (nípa ìyà wọn). info
التفاسير:

external-link copy
60 : 51

فَوَيۡلٞ لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ مِن يَوۡمِهِمُ ٱلَّذِي يُوعَدُونَ

Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn. info
التفاسير: