《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译 - 艾布·拉西麦·米卡依赖。

页码:close

external-link copy
36 : 50

وَكَمۡ أَهۡلَكۡنَا قَبۡلَهُم مِّن قَرۡنٍ هُمۡ أَشَدُّ مِنۡهُم بَطۡشٗا فَنَقَّبُواْ فِي ٱلۡبِلَٰدِ هَلۡ مِن مَّحِيصٍ

Mélòó mélòó nínú àwọn ìjọ tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Wọ́n sì ní agbára jù wọ́n lọ. (Nígbà tí ìyà dé) wọ́n sá àsálà kiri nínú ìlú. Ǹjẹ́ ibùsásí kan wà (fún wọn bí?) info
التفاسير:

external-link copy
37 : 50

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَذِكۡرَىٰ لِمَن كَانَ لَهُۥ قَلۡبٌ أَوۡ أَلۡقَى ٱلسَّمۡعَ وَهُوَ شَهِيدٞ

Dájúdájú ìrántí wà nínú ìyẹn fún ẹni tó ní ọkàn tàbí ẹni tó fi etí sílẹ̀, tó wà níbẹ̀ (pẹ̀lú ọkàn rẹ̀). info
التفاسير:

external-link copy
38 : 50

وَلَقَدۡ خَلَقۡنَا ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَا فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ وَمَا مَسَّنَا مِن لُّغُوبٖ

Dájúdájú A ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin àwọn méjèèjì fún ọjọ́ mẹ́fà. Kò sì rẹ̀ Wá rárá (áḿbọ̀sìbọ́sí pé A óò sinmi ní ọjọ́ keje). info
التفاسير:

external-link copy
39 : 50

فَٱصۡبِرۡ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ قَبۡلَ طُلُوعِ ٱلشَّمۡسِ وَقَبۡلَ ٱلۡغُرُوبِ

Nítorí náà, ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí. Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa Rẹ[1] ṣíwájú yíyọ òòrùn àti wíwọ̀ (rẹ̀). info

1. Ìyẹn ni pé, ṣe àfọ̀mọ́ Allāhu kúrò níbi gbogbo àdínkù àti àbùkù, kí o sì yìn Ín lógo pé, O pé tán pátápátá.

التفاسير:

external-link copy
40 : 50

وَمِنَ ٱلَّيۡلِ فَسَبِّحۡهُ وَأَدۡبَٰرَ ٱلسُّجُودِ

Àti pé ní òru àti ni ẹ̀yìn ìrun ṣe àfọ̀mọ́ fún Un. info
التفاسير:

external-link copy
41 : 50

وَٱسۡتَمِعۡ يَوۡمَ يُنَادِ ٱلۡمُنَادِ مِن مَّكَانٖ قَرِيبٖ

Kí o sì tẹ́tí sí (ọ̀rọ̀) ọjọ́ tí olùpèpè yóò pèpè láti àyè kan tó súnmọ́. info
التفاسير:

external-link copy
42 : 50

يَوۡمَ يَسۡمَعُونَ ٱلصَّيۡحَةَ بِٱلۡحَقِّۚ ذَٰلِكَ يَوۡمُ ٱلۡخُرُوجِ

Ọjọ́ tí wọn yóò gbọ́ igbe pẹ̀lú òdodo. Ìyẹn ni ọjọ́ ìjáde ẹ̀dá (láti inú sàréè). info
التفاسير:

external-link copy
43 : 50

إِنَّا نَحۡنُ نُحۡيِۦ وَنُمِيتُ وَإِلَيۡنَا ٱلۡمَصِيرُ

Dájúdájú Àwa, Àwa l’À ń sọ ẹ̀dá di alààyè. A sì ń sọ ọ́ di òkú. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni àbọ̀ ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
44 : 50

يَوۡمَ تَشَقَّقُ ٱلۡأَرۡضُ عَنۡهُمۡ سِرَاعٗاۚ ذَٰلِكَ حَشۡرٌ عَلَيۡنَا يَسِيرٞ

(Rántí) ọjọ́ tí ilẹ̀ yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ mọ́ wọn lára, (tí wọn yóò máa) yára (jáde láti inú ilẹ̀). Ìyẹn ni àkójọ tó rọrùn fún Wa. info
التفاسير:

external-link copy
45 : 50

نَّحۡنُ أَعۡلَمُ بِمَا يَقُولُونَۖ وَمَآ أَنتَ عَلَيۡهِم بِجَبَّارٖۖ فَذَكِّرۡ بِٱلۡقُرۡءَانِ مَن يَخَافُ وَعِيدِ

Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń wí. Ìwọ kò sì níí jẹ wọ́n nípá (láti gbàgbọ́). Nítorí náà, fi al-Ƙur’ān ṣe ìrántí fún ẹni tí ó ń páyà ìlérí Mi. info
التفاسير: