《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译 - 艾布·拉西麦·米卡依赖。

external-link copy
92 : 4

وَمَا كَانَ لِمُؤۡمِنٍ أَن يَقۡتُلَ مُؤۡمِنًا إِلَّا خَطَـٔٗاۚ وَمَن قَتَلَ مُؤۡمِنًا خَطَـٔٗا فَتَحۡرِيرُ رَقَبَةٖ مُّؤۡمِنَةٖ وَدِيَةٞ مُّسَلَّمَةٌ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦٓ إِلَّآ أَن يَصَّدَّقُواْۚ فَإِن كَانَ مِن قَوۡمٍ عَدُوّٖ لَّكُمۡ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَتَحۡرِيرُ رَقَبَةٖ مُّؤۡمِنَةٖۖ وَإِن كَانَ مِن قَوۡمِۭ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَهُم مِّيثَٰقٞ فَدِيَةٞ مُّسَلَّمَةٌ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦ وَتَحۡرِيرُ رَقَبَةٖ مُّؤۡمِنَةٖۖ فَمَن لَّمۡ يَجِدۡ فَصِيَامُ شَهۡرَيۡنِ مُتَتَابِعَيۡنِ تَوۡبَةٗ مِّنَ ٱللَّهِۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمٗا

Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún onígbàgbọ́ òdodo kan láti pa onígbàgbọ́ òdodo kan àyàfi tí ó bá ṣèèsì. Ẹni tí ó bá sì ṣèèsì pa onígbàgbọ́ òdodo kan, ó máa tú ẹrú lónígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ó tún máa san owó ẹ̀mí fún àwọn ènìyàn òkú àfi tí wọ́n bá fi tọrẹ (fún un, tí wọ́n bá yọ̀ǹda rẹ̀ fún un). Tí ó bá sì wà nínú àwọn ènìyàn kan tí ó jẹ́ ọ̀tá fún yín, onígbàgbọ́ sì ni (ẹni tí wọ́n ṣèèsì pa), ó máa tú ẹrú lónígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Tí ó bá jẹ́ ìjọ tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn (ni ẹni tí wọ́n ṣèèsì pa), ó máa san owó ẹ̀mí fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó tún máa tú ẹrú lónígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ẹni tí kò bá rí (ẹrú lónígbàgbọ́ òdodo), ó máa gba ààwẹ̀ oṣù méjì ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. (Ọ̀nà) ìronúpìwàdà kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu (nìyí). Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. info
التفاسير: