《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译 - 艾布·拉西麦·米卡依赖。

external-link copy
90 : 4

إِلَّا ٱلَّذِينَ يَصِلُونَ إِلَىٰ قَوۡمِۭ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَهُم مِّيثَٰقٌ أَوۡ جَآءُوكُمۡ حَصِرَتۡ صُدُورُهُمۡ أَن يُقَٰتِلُوكُمۡ أَوۡ يُقَٰتِلُواْ قَوۡمَهُمۡۚ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَسَلَّطَهُمۡ عَلَيۡكُمۡ فَلَقَٰتَلُوكُمۡۚ فَإِنِ ٱعۡتَزَلُوكُمۡ فَلَمۡ يُقَٰتِلُوكُمۡ وَأَلۡقَوۡاْ إِلَيۡكُمُ ٱلسَّلَمَ فَمَا جَعَلَ ٱللَّهُ لَكُمۡ عَلَيۡهِمۡ سَبِيلٗا

Àyàfi àwọn tó bá darapọ̀ mọ́ ìjọ kan tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn. Tàbí wọ́n wá ba yín, tí ọkàn wọn ti pami láti ba yín jà tàbí láti bá àwọn ènìyàn wọn jà. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá fún wọn lágbára (ọkàn-akin) lórí yín, wọn ìbá sì jà yín lógun. Nítorí náà, tí wọ́n bá yẹra fún yín, tí wọn kò sì jà yín lógun, tí wọ́n sì juwọ́ sílẹ̀ fún yín, nígbà náà Allāhu kò fún yín ní ọ̀nà lórí wọn (láti jà wọ́n lógun). info
التفاسير: