《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译 - 艾布·拉西麦·米卡依赖。

Al-Kah'f

external-link copy
1 : 18

ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ عَلَىٰ عَبۡدِهِ ٱلۡكِتَٰبَ وَلَمۡ يَجۡعَل لَّهُۥ عِوَجَاۜ

Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀. Kò sì dojú ọ̀rọ̀ kan rú nínú rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
2 : 18

قَيِّمٗا لِّيُنذِرَ بَأۡسٗا شَدِيدٗا مِّن لَّدُنۡهُ وَيُبَشِّرَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٱلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلصَّٰلِحَٰتِ أَنَّ لَهُمۡ أَجۡرًا حَسَنٗا

(Ó ṣe é ni tírà) tó dúró déédé[1] nítorí kí (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) lè fi ṣe ìkìlọ̀ ìyà líle láti ọ̀dọ̀ (Allāhu) àti nítorí kí ó lè fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo, àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú ẹ̀san rere ń bẹ fún wọn (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra); info

1. Ìyẹn ni pé, al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé jẹ́ tírà tí kì í gbèfún ìbàjẹ́, irọ́, àbòsí àti ìsọkúsọ.

التفاسير:

external-link copy
3 : 18

مَّٰكِثِينَ فِيهِ أَبَدٗا

Wọn yóò máa gbé nínú rẹ̀ lọ títí láéláé. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 18

وَيُنذِرَ ٱلَّذِينَ قَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱللَّهُ وَلَدٗا

Àti nítorí kí ó lè ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn tó wí pé: “Allāhu mú ẹnì kan ní ọmọ.” info
التفاسير: