Salin ng mga Kahulugan ng Marangal na Qur'an - Salin sa Wikang Yoruba ni Abu Rahima Mikhail

Numero ng Pahina:close

external-link copy
196 : 7

إِنَّ وَلِـِّۧيَ ٱللَّهُ ٱلَّذِي نَزَّلَ ٱلۡكِتَٰبَۖ وَهُوَ يَتَوَلَّى ٱلصَّٰلِحِينَ

Dájúdájú Alátìlẹ́yìn mi ni Allāhu, Ẹni tí Ó sọ Tírà náà kalẹ̀. Àti pé Òun l’Ó ń ṣàtìlẹ́yìn fún àwọn ẹni rere. info
التفاسير:

external-link copy
197 : 7

وَٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦ لَا يَسۡتَطِيعُونَ نَصۡرَكُمۡ وَلَآ أَنفُسَهُمۡ يَنصُرُونَ

Àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè ṣe àrànṣe fún yín. Wọn kò sì lè ṣe àrànṣe fún ẹ̀mí ara wọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
198 : 7

وَإِن تَدۡعُوهُمۡ إِلَى ٱلۡهُدَىٰ لَا يَسۡمَعُواْۖ وَتَرَىٰهُمۡ يَنظُرُونَ إِلَيۡكَ وَهُمۡ لَا يُبۡصِرُونَ

Tí ẹ bá sì pè wọ́n sínú ìmọ̀nà, wọn kò níí gbọ́. Ò ń rí wọn pé wọ́n ń wò ọ́ ni, (ṣùgbọ́n) wọn kò ríran. info
التفاسير:

external-link copy
199 : 7

خُذِ ٱلۡعَفۡوَ وَأۡمُرۡ بِٱلۡعُرۡفِ وَأَعۡرِضۡ عَنِ ٱلۡجَٰهِلِينَ

Ṣàmójúkúrò, pàṣẹ ohun rere, kí o sì ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìmọ̀kan. info
التفاسير:

external-link copy
200 : 7

وَإِمَّا يَنزَغَنَّكَ مِنَ ٱلشَّيۡطَٰنِ نَزۡغٞ فَٱسۡتَعِذۡ بِٱللَّهِۚ إِنَّهُۥ سَمِيعٌ عَلِيمٌ

Tí ìbínú òdì kan bá sì ṣẹ́rí sínú ọkàn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ aṣ-Ṣaetọ̄n, fi Allāhu wá ìṣọ́rí. Dájúdájú Òun ní Olùgbọ́, Onímọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
201 : 7

إِنَّ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ إِذَا مَسَّهُمۡ طَٰٓئِفٞ مِّنَ ٱلشَّيۡطَٰنِ تَذَكَّرُواْ فَإِذَا هُم مُّبۡصِرُونَ

Dájúdájú àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu), nígbà tí ròyíròyí kan bá ṣẹlẹ̀ sí wọn láti ọ̀dọ̀ aṣ-Ṣaetọ̄n, tí wọ́n bá rántí (Allāhu), nígbà náà ojú wọn yó sì ríran (rí òdodo). info
التفاسير:

external-link copy
202 : 7

وَإِخۡوَٰنُهُمۡ يَمُدُّونَهُمۡ فِي ٱلۡغَيِّ ثُمَّ لَا يُقۡصِرُونَ

(Àmọ́ ní ti) àwọn ọmọ ìyá (aṣ-Ṣaetọ̄n), ńṣe ni àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n yóò máa kún wọn lọ́wọ́ nínú ìṣìnà. Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí dáràn mọ níwọ̀n. info
التفاسير:

external-link copy
203 : 7

وَإِذَا لَمۡ تَأۡتِهِم بِـَٔايَةٖ قَالُواْ لَوۡلَا ٱجۡتَبَيۡتَهَاۚ قُلۡ إِنَّمَآ أَتَّبِعُ مَا يُوحَىٰٓ إِلَيَّ مِن رَّبِّيۚ هَٰذَا بَصَآئِرُ مِن رَّبِّكُمۡ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٞ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ

Nígbà tí o ò bá mú àmì wá bá wọn, wọ́n á wí pé: “Ìwọ kò ṣe ṣe àdáhun rẹ̀?” Sọ pé: “Ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi ni mò ń tẹ̀lé. (al-Ƙur’ān) yìí sì ni ìmọ̀ àmọ̀dájú àti ẹ̀rí láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Ìmọ̀nà àti ìkẹ́ sì ni fún àwọn ìjọ onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
204 : 7

وَإِذَا قُرِئَ ٱلۡقُرۡءَانُ فَٱسۡتَمِعُواْ لَهُۥ وَأَنصِتُواْ لَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ

Nígbà tí wọ́n ba ń ke al-Ƙur’ān, ẹ tẹ́tí sí i, kí ẹ sì dákẹ́ nítorí kí A lè kẹ yín. info
التفاسير:

external-link copy
205 : 7

وَٱذۡكُر رَّبَّكَ فِي نَفۡسِكَ تَضَرُّعٗا وَخِيفَةٗ وَدُونَ ٱلۡجَهۡرِ مِنَ ٱلۡقَوۡلِ بِٱلۡغُدُوِّ وَٱلۡأٓصَالِ وَلَا تَكُن مِّنَ ٱلۡغَٰفِلِينَ

Ṣe ìrántí Olúwa Rẹ nínú ẹ̀mí rẹ pẹ̀lú ìrawọ́rasẹ̀ àti ìbẹ̀rù (Allāhu), kò sì níí jẹ́ ọ̀rọ̀ ariwo, ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́. Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn olùgbàgbéra (nípa ìrántí Allāhu). info
التفاسير:

external-link copy
206 : 7

إِنَّ ٱلَّذِينَ عِندَ رَبِّكَ لَا يَسۡتَكۡبِرُونَ عَنۡ عِبَادَتِهِۦ وَيُسَبِّحُونَهُۥ وَلَهُۥ يَسۡجُدُونَۤ۩

Dájúdájú àwọn tó ń bẹ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ, wọn kì í jọra wọn lójú láti jọ́sìn fún Un. Wọ́n ń ṣàfọ̀mọ́ fún Un. Wọ́n sì ń forí kanlẹ̀ fún Un. info
التفاسير: