Salin ng mga Kahulugan ng Marangal na Qur'an - Salin sa Wikang Yoruba ni Abu Rahima Mikhail

Numero ng Pahina: 148:128 close

external-link copy
152 : 6

وَلَا تَقۡرَبُواْ مَالَ ٱلۡيَتِيمِ إِلَّا بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُ حَتَّىٰ يَبۡلُغَ أَشُدَّهُۥۚ وَأَوۡفُواْ ٱلۡكَيۡلَ وَٱلۡمِيزَانَ بِٱلۡقِسۡطِۖ لَا نُكَلِّفُ نَفۡسًا إِلَّا وُسۡعَهَاۖ وَإِذَا قُلۡتُمۡ فَٱعۡدِلُواْ وَلَوۡ كَانَ ذَا قُرۡبَىٰۖ وَبِعَهۡدِ ٱللَّهِ أَوۡفُواْۚ ذَٰلِكُمۡ وَصَّىٰكُم بِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَذَكَّرُونَ

Ẹ má ṣe súnmọ́ dúkìá ọmọ òrukàn àyàfi ní ọ̀nà tó dára jùlọ títí ó fi máa dàgbà dáadáa. Ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n kún ní dọ́gban̄dọ́gba.A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àyàfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Tí ẹ bá sọ̀rọ̀, ẹ ṣe déédé, ìbáà jẹ́ pé ó tabá ìbátan. Kí ẹ sì pé àdéhùn Allāhu. Ìyẹn l’Ó pa láṣẹ fún yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí. info
التفاسير:

external-link copy
153 : 6

وَأَنَّ هَٰذَا صِرَٰطِي مُسۡتَقِيمٗا فَٱتَّبِعُوهُۖ وَلَا تَتَّبِعُواْ ٱلسُّبُلَ فَتَفَرَّقَ بِكُمۡ عَن سَبِيلِهِۦۚ ذَٰلِكُمۡ وَصَّىٰكُم بِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَتَّقُونَ

Àti pé dájúdájú èyí ni ọ̀nà Mi (tí ó jẹ́ ọ̀nà) tààrà. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé e. Ẹ má ṣe tẹ̀lé àwọn ojú ọ̀nà (mìíràn) nítorí kí ó má baà mu yín yapa ojú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀. Ìyẹn l’Ó pa láṣẹ fún yín nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Rẹ̀).” info
التفاسير:

external-link copy
154 : 6

ثُمَّ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ تَمَامًا عَلَى ٱلَّذِيٓ أَحۡسَنَ وَتَفۡصِيلٗا لِّكُلِّ شَيۡءٖ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٗ لَّعَلَّهُم بِلِقَآءِ رَبِّهِمۡ يُؤۡمِنُونَ

Lẹ́yìn náà, A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà ní pípé pérépéré fún ẹni tí ó máa ṣe dáadáa. (Ó jẹ́) àlàyé fún gbogbo n̄ǹkan. (Ó tún jẹ́) ìmọ̀nà àti ìkẹ́ nítorí kí wọ́n lè ní ìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn. info
التفاسير:

external-link copy
155 : 6

وَهَٰذَا كِتَٰبٌ أَنزَلۡنَٰهُ مُبَارَكٞ فَٱتَّبِعُوهُ وَٱتَّقُواْ لَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ

Èyí ni Tírà ìbùkún tí A sọ̀kalẹ̀. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé e. Kí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu) nítorí kí A lè kẹ yín. info
التفاسير:

external-link copy
156 : 6

أَن تَقُولُوٓاْ إِنَّمَآ أُنزِلَ ٱلۡكِتَٰبُ عَلَىٰ طَآئِفَتَيۡنِ مِن قَبۡلِنَا وَإِن كُنَّا عَن دِرَاسَتِهِمۡ لَغَٰفِلِينَ

Nítorí kí ẹ má ṣe wí pé: “Ọ̀wọ́ ìjọ méjì tí ó ṣíwájú wa ni wọ́n sọ Tírà kalẹ̀ fún. A sì jẹ́ aláìnímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ wọn.” info
التفاسير:

external-link copy
157 : 6

أَوۡ تَقُولُواْ لَوۡ أَنَّآ أُنزِلَ عَلَيۡنَا ٱلۡكِتَٰبُ لَكُنَّآ أَهۡدَىٰ مِنۡهُمۡۚ فَقَدۡ جَآءَكُم بَيِّنَةٞ مِّن رَّبِّكُمۡ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٞۚ فَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن كَذَّبَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَصَدَفَ عَنۡهَاۗ سَنَجۡزِي ٱلَّذِينَ يَصۡدِفُونَ عَنۡ ءَايَٰتِنَا سُوٓءَ ٱلۡعَذَابِ بِمَا كَانُواْ يَصۡدِفُونَ

Tàbí kí ẹ má baà wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n sọ Tírà kalẹ̀ fún wa ni, àwa ìbá mọ̀nà jù wọ́n lọ.” Ẹ̀rí tó yanjú, ìmọ̀nà àti ìkẹ́ kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, kò sí ẹni tó ṣàbòsí tó ẹni tó pe àwọn āyah Allāhu nírọ́, tó tún gbúnrí kúrò níbẹ̀? A máa san àwọn tó ń gbúnrí kúrò níbi àwọn āyah Wa ní (ẹ̀san) ìyà burúkú nítorí pé wọ́n ń gbúnrí (kúrò níbẹ̀). info
التفاسير: