Salin ng mga Kahulugan ng Marangal na Qur'an - Salin sa Wikang Yoruba ni Abu Rahima Mikhail

external-link copy
15 : 29

فَأَنجَيۡنَٰهُ وَأَصۡحَٰبَ ٱلسَّفِينَةِ وَجَعَلۡنَٰهَآ ءَايَةٗ لِّلۡعَٰلَمِينَ

A sì la òun àti àwọn èrò inú ọkọ̀ ojú-omi. A sì ṣe wọ́n ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá.[1] info

1. Ǹjẹ́ ẹnì kan lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ Ànábì Nūh - kí ọlà Allāhu máa bá a - di olúwa àti olùgbàlà nítorí pé Allāhu sọ nípa rẹ̀ pé “A sì ṣe wọ́n ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá”? Rárá. Kí ló wá rọ́lu àwọn kan tí wọ́n sọ Ànábì Īsā di olùgbàlà?

التفاسير: