Salin ng mga Kahulugan ng Marangal na Qur'an - Salin sa Wikang Yoruba ni Abu Rahima Mikhail

external-link copy
95 : 17

قُل لَّوۡ كَانَ فِي ٱلۡأَرۡضِ مَلَٰٓئِكَةٞ يَمۡشُونَ مُطۡمَئِنِّينَ لَنَزَّلۡنَا عَلَيۡهِم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ مَلَكٗا رَّسُولٗا

Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn mọlāika wà lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n ń rìn kiri, (tí wọ́n ń gbé lórí ilẹ̀) pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀, A ìbá sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún wọn láti inú sánmọ̀ (láti jẹ́) Òjíṣẹ́.”[1] info

1. Ìyẹn ni pé, irọ́ ńlá ni láti ẹnu àwọn nasọ̄rọ̄ láti sọ pé Ọlọ́hun fúnra Rẹ̀ l’ó wá jíṣẹ́ ara Rẹ̀ ní àwòrán ‘Īsā ọmọ Mọryam láààrin àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl! Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń sọ nípa Rẹ̀ ní irọ́.

التفاسير: