1. “níwájú wọn” túmọ̀ sí pé àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ọlà Allāhu máa bá wọn - wá bá àwọn bàbá ńlá wọn, “lẹ́yìn wọn” sì túmọ̀ sí pé àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu tún wá bá àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn lẹ́yìn ìparun àwọn bàbá ńlá wọn.
1. Àwọn “nasọ̄rọ̄ sọ pé, “Nínú sūrah al-Ƙọmọr; 54:19, Allāhu dárúkọ ọjọ́ kan fún ìparun ìjọ ‘Ād. Àmọ́ nínú sūrah al-Hāƙƙọh; 69:7, Allāhu dárúkọ òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ fún ìparun wọn. Nínú sūrah Fussilat; 41:16, Allāhu dárúkọ àwọn ọjọ́? Wọ́n ní, “Nítorí náà, ìtakora ti jẹyọ lórí òǹkà ọjọ́ ti Allāhu fi pa ìjọ ‘Ād run! Èsì: Kò sí ìtakora láààrin àwọn āyah náà. Àlàyé rẹ̀ nìyí, āyah ti sūrah al-Ƙọmọr tó pè é ní ọjọ́ kan sọ pé “ọjọ́ burúkú kan tó ń tẹ̀ síwájú.” Nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀, “ọjọ́ kan” di “àwọn ọjọ́ kan” nínú āyah ti sūrah Fussilat. Àmọ́ àpapọ̀ òǹkà ọjọ́ ìparun wọn l’ó jẹyọ nínú āyah ti sūrah al-Hāƙƙọh. Ṣé ẹ ti rí i báyìí pé, àìnímọ̀ nípa èto láààrin àwọn āyah lè ṣokùnfà ìtakora āyah lójú àwọn aláìmọ̀kan.
1. Ìyẹn nípasẹ̀ pé Allāhu - Ọba tó ga jùlọ - rán àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sí wọn.