1. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan nínú àwọn onímọ̀ ’Islām máa ń sọ pé irúfẹ́ àwọn lẹ́tà (háràfí) wọ̀nyí dúró fún àwọn ọ̀rọ̀ kan, ohun tí àwọn onímọ̀ ’Islām faramọ́ jùlọ ni pé, Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - nìkan ṣoṣo l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn harafi náà.
1. Ìkọ̀kọ̀ ni ohun tí ẹ̀dá kò lè fi ọ̀nà kan kan nímọ̀ nípa rẹ̀ nínú ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ - sọllallāhu alaehi wa sallam - sọ nípa rẹ̀.
1. Ní àkọ́kọ́ ná, Allāhu kò dárúkọ bíbélì nínú al-Ƙur’ān. Orúkọ àwọn tírà mímọ́ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sọ nípa wọn nínú al-Ƙur’ān ni Zabūr, Suhuf, Taorāt àti ’Injīl. Lẹ́yìn náà, Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fi rinlẹ̀ nínú al-Ƙur’ān pé kò sí ojúlówó àwọn tírà náà mọ́ níta, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:75 & 79, sūrah an-Nisā’; 4:46 àti sūrah al-Mọ̄’idah; 5:13. Nítorí náà, al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé ni tírà ìkẹ́yìn láti ọ̀dọ̀ Allāhu fún gbogbo ẹ̀dá. Kò sí òmíràn mọ́.