அல்குர்ஆன் மொழிபெயர்ப்பு - யொரூபா மொழிபெயர்ப்பு - அபூ ரஹீமா மிக்கேல்

Al-Gaashiyah

external-link copy
1 : 88

هَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ ٱلۡغَٰشِيَةِ

Ṣebí ọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ ti dé ọ̀dọ̀ rẹ? info
التفاسير:

external-link copy
2 : 88

وُجُوهٞ يَوۡمَئِذٍ خَٰشِعَةٌ

Àwọn ojú kan yóò wálẹ̀ (ní ti ìyẹpẹrẹ) ní ọjọ́ yẹn. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 88

عَامِلَةٞ نَّاصِبَةٞ

Wọ́n ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó (ni nílé ayé). info
التفاسير:

external-link copy
4 : 88

تَصۡلَىٰ نَارًا حَامِيَةٗ

Wọ́n sì máa wọ inú Iná tó gbóná janjan (ní ọ̀run). info
التفاسير:

external-link copy
5 : 88

تُسۡقَىٰ مِنۡ عَيۡنٍ ءَانِيَةٖ

Wọ́n sì máa fún (wọn) ní omi ìṣẹ́lẹ̀rú gbígbóná mu. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 88

لَّيۡسَ لَهُمۡ طَعَامٌ إِلَّا مِن ضَرِيعٖ

Kò sí oúnjẹ kan fún wọn àyàfi igi ẹlẹ́gùn-ún gbígbẹ. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 88

لَّا يُسۡمِنُ وَلَا يُغۡنِي مِن جُوعٖ

Kò níí mú wọn sanra. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ebi. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 88

وُجُوهٞ يَوۡمَئِذٖ نَّاعِمَةٞ

Àwọn ojú kan yó sì kún fún ìgbádùn ní ọjọ́ yẹn info
التفاسير:

external-link copy
9 : 88

لِّسَعۡيِهَا رَاضِيَةٞ

nítorí pé (ó) yọ́nú sí (ẹ̀san) iṣẹ́ rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
10 : 88

فِي جَنَّةٍ عَالِيَةٖ

(Ó máa) wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga. info
التفاسير:

external-link copy
11 : 88

لَّا تَسۡمَعُ فِيهَا لَٰغِيَةٗ

Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
12 : 88

فِيهَا عَيۡنٞ جَارِيَةٞ

Omi ìṣẹ́lẹ̀rú tó ń ṣàn wà nínú rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
13 : 88

فِيهَا سُرُرٞ مَّرۡفُوعَةٞ

Àwọn ibùsùn tí wọ́n gbé sókè wà nínú rẹ̀, info
التفاسير:

external-link copy
14 : 88

وَأَكۡوَابٞ مَّوۡضُوعَةٞ

àti àwọn ife ìmumi tí wọ́n gbé kalẹ̀ (sí àrọ́wọ́tó wọn), info
التفاسير:

external-link copy
15 : 88

وَنَمَارِقُ مَصۡفُوفَةٞ

àti àwọn ìrọ̀rí tí wọ́n tò sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn, info
التفاسير:

external-link copy
16 : 88

وَزَرَابِيُّ مَبۡثُوثَةٌ

àti àwọn ìtẹ́ àtẹ́ẹ̀ká. info
التفاسير:

external-link copy
17 : 88

أَفَلَا يَنظُرُونَ إِلَى ٱلۡإِبِلِ كَيۡفَ خُلِقَتۡ

Nítorí náà, ṣé wọn kò wòye sí ràkúnmí, bí A ti ṣẹ̀dá rẹ̀ ni; info
التفاسير:

external-link copy
18 : 88

وَإِلَى ٱلسَّمَآءِ كَيۡفَ رُفِعَتۡ

àti sánmọ̀, bí A ti ṣe gbé e sókè; info
التفاسير:

external-link copy
19 : 88

وَإِلَى ٱلۡجِبَالِ كَيۡفَ نُصِبَتۡ

àti àpáta, bí A ti ṣe gbé e nàró (sínú ilẹ̀); info
التفاسير:

external-link copy
20 : 88

وَإِلَى ٱلۡأَرۡضِ كَيۡفَ سُطِحَتۡ

àti ilẹ̀, bí A ti ṣe tẹ́ ẹ sílẹ̀ pẹrẹsẹ? info
التفاسير:

external-link copy
21 : 88

فَذَكِّرۡ إِنَّمَآ أَنتَ مُذَكِّرٞ

Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kúkú ni olùṣèràntí. info
التفاسير:

external-link copy
22 : 88

لَّسۡتَ عَلَيۡهِم بِمُصَيۡطِرٍ

Ìwọ kì í ṣe ajẹni-nípá lórí wọn info
التفاسير:

external-link copy
23 : 88

إِلَّا مَن تَوَلَّىٰ وَكَفَرَ

àfi ẹni tí ó bá pẹ̀yìndà (sí òdodo), tí ó sì ṣàì gbàgbọ́. info
التفاسير:

external-link copy
24 : 88

فَيُعَذِّبُهُ ٱللَّهُ ٱلۡعَذَابَ ٱلۡأَكۡبَرَ

Allāhu sì máa jẹ ẹ́ níyà tó tóbi jùlọ. info
التفاسير:

external-link copy
25 : 88

إِنَّ إِلَيۡنَآ إِيَابَهُمۡ

Dájúdájú ọ̀dọ̀ Wa ni àbọ̀ wọn wà. info
التفاسير:

external-link copy
26 : 88

ثُمَّ إِنَّ عَلَيۡنَا حِسَابَهُم

Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ wọn. info
التفاسير: