1. Ìyẹn ni pé, nínú Iná, yàtọ̀ sí pé oríṣiríṣi omi burúkú l’ó wà nínú rẹ̀ bíi omi tó gbóná parí, omi rẹ́funrẹ́fun, omi ètútú, omi àwọnúwẹ̀jẹ̀, àwọn omi wọ̀nyí máa wà nínú ọ̀gbun kan fún àwọn ọmọ Iná nínú Iná, bí Iná bá ti ń jó wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n á lọ máa mu omi ìmukúmu wọ̀nyí sí i, wọ́n á tún padà síbi Iná, wọ́n á tún padà síbi omi, wọ́n á tún padà síbi Ina. Wọ́n á wà bẹ́ẹ̀ títí láéláé.