1. Nítorí kí a lè mọ ìdí pàtàkì tí Allāhu ṣe fi sūrah yìí sọrí mọ̀lẹ́bí ‘Imrọ̄n, òbí Mọryam, ìyá Ànábì ‘Isā - kí ọlà Allāhu máa bá a -, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Mọryam. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.
1. Gbólóhùn yìí níí ṣepọ̀ pẹ̀lú ìjọ àti àsìkò. 2. Fún àlàyé lórí al-Furƙọ̄n, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:53.
1. Ìyẹn ni pé, a óò máa fi àwọn āyah aláìnípọ́n-na yanjú àwọn āyah onípọ́n-na. 2. Pọ́n-na ni kí ìsọ tàbí ọ̀rọ̀ ṣe é túmọ̀ sí ọ̀pọ̀ ọ̀nà, yálà ìtúmọ̀ tí wọ́n gbà lérò tàbí ìtúmọ̀ tí wọn kò gbà lérò.