د قرآن کریم د معناګانو ژباړه - یورباوي ژباړه - أبو رحیمة میکائیل

د مخ نمبر:close

external-link copy
52 : 15

إِذۡ دَخَلُواْ عَلَيۡهِ فَقَالُواْ سَلَٰمٗا قَالَ إِنَّا مِنكُمۡ وَجِلُونَ

(Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́, wọ́n sì sọ pé: “Àlàáfíà”. Ó sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀rù yín ń ba àwa.” info
التفاسير:

external-link copy
53 : 15

قَالُواْ لَا تَوۡجَلۡ إِنَّا نُبَشِّرُكَ بِغُلَٰمٍ عَلِيمٖ

Wọ́n sọ pé: “Má ṣe bẹ̀rù. Dájúdájú àwa yóò fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan tí ó máa ní ìmọ̀.” info
التفاسير:

external-link copy
54 : 15

قَالَ أَبَشَّرۡتُمُونِي عَلَىٰٓ أَن مَّسَّنِيَ ٱلۡكِبَرُ فَبِمَ تُبَشِّرُونَ

Ó sọ pé: “Ṣé ẹ̀ ń fún mi ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí ọmọ) nígbà tí ogbó ti dé sí mi? Ìró ìdùnnú wo ni ẹ̀ ń fún mi ná?” info
التفاسير:

external-link copy
55 : 15

قَالُواْ بَشَّرۡنَٰكَ بِٱلۡحَقِّ فَلَا تَكُن مِّنَ ٱلۡقَٰنِطِينَ

Wọ́n sọ pé: “À ń fún ọ ní ìró ìdùnnú pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, má ṣe wà lára àwọn olùjákànmùná.” info
التفاسير:

external-link copy
56 : 15

قَالَ وَمَن يَقۡنَطُ مِن رَّحۡمَةِ رَبِّهِۦٓ إِلَّا ٱلضَّآلُّونَ

Ó sọ pé: “Kò mà sí ẹni tí ó máa jákànmùná nínú ìkẹ́ Olúwa Rẹ̀ bí kò ṣe àwọn olùṣìnà.” info
التفاسير:

external-link copy
57 : 15

قَالَ فَمَا خَطۡبُكُمۡ أَيُّهَا ٱلۡمُرۡسَلُونَ

Ó sọ pé: “Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́?” info
التفاسير:

external-link copy
58 : 15

قَالُوٓاْ إِنَّآ أُرۡسِلۡنَآ إِلَىٰ قَوۡمٖ مُّجۡرِمِينَ

Wọ́n sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni. info
التفاسير:

external-link copy
59 : 15

إِلَّآ ءَالَ لُوطٍ إِنَّا لَمُنَجُّوهُمۡ أَجۡمَعِينَ

Àfi ará ilé (Ànábì) Lūt. Dájúdájú àwa yóò gba wọn là pátápátá. info
التفاسير:

external-link copy
60 : 15

إِلَّا ٱمۡرَأَتَهُۥ قَدَّرۡنَآ إِنَّهَا لَمِنَ ٱلۡغَٰبِرِينَ

Àfi ìyàwó rẹ̀; A ti kọ kádàrá rẹ̀ (pé) dájúdájú ó máa wà nínú àwọn tó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun.” info
التفاسير:

external-link copy
61 : 15

فَلَمَّا جَآءَ ءَالَ لُوطٍ ٱلۡمُرۡسَلُونَ

Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ dé ọ̀dọ̀ ará ilé (Ànábì) Lūt, info
التفاسير:

external-link copy
62 : 15

قَالَ إِنَّكُمۡ قَوۡمٞ مُّنكَرُونَ

(Ànábì Lūt) sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin jẹ́ àjòjì ènìyàn.” info
التفاسير:

external-link copy
63 : 15

قَالُواْ بَلۡ جِئۡنَٰكَ بِمَا كَانُواْ فِيهِ يَمۡتَرُونَ

Wọ́n sọ pé: “Rárá, a wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ohun tí wọ́n ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
64 : 15

وَأَتَيۡنَٰكَ بِٱلۡحَقِّ وَإِنَّا لَصَٰدِقُونَ

A mú òdodo wá bá ọ ni. Àti pé dájúdájú olódodo ni àwa. info
التفاسير:

external-link copy
65 : 15

فَأَسۡرِ بِأَهۡلِكَ بِقِطۡعٖ مِّنَ ٱلَّيۡلِ وَٱتَّبِعۡ أَدۡبَٰرَهُمۡ وَلَا يَلۡتَفِتۡ مِنكُمۡ أَحَدٞ وَٱمۡضُواْ حَيۡثُ تُؤۡمَرُونَ

Nítorí náà, mú ará ilé rẹ jáde ní apá kan òru. Kí o sì tẹ̀lé wọn lẹ́yìn. Ẹnì kan nínú yín kò sì gbọdọ̀ ṣíjú wo ẹ̀yìn wò. Kí ẹ sì lọ sí àyè tí wọ́n ń pa láṣẹ fún yín.” info
التفاسير:

external-link copy
66 : 15

وَقَضَيۡنَآ إِلَيۡهِ ذَٰلِكَ ٱلۡأَمۡرَ أَنَّ دَابِرَ هَٰٓؤُلَآءِ مَقۡطُوعٞ مُّصۡبِحِينَ

A sì jẹ́ kí ìdájọ́ ọ̀rọ̀ yìí hàn sí i pé dájúdájú A máa pa àwọn (ẹlẹ́ṣẹ̀) wọ̀nyí run pátápátá nígbà tí wọ́n bá mọ́júmọ́. info
التفاسير:

external-link copy
67 : 15

وَجَآءَ أَهۡلُ ٱلۡمَدِينَةِ يَسۡتَبۡشِرُونَ

Àwọn ará ìlú náà dé, wọ́n sì ń yọ̀ sẹ̀sẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
68 : 15

قَالَ إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ ضَيۡفِي فَلَا تَفۡضَحُونِ

(Ànábì Lūt) sọ pé: “Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni àlejò mi. Nítorí náà, ẹ má ṣe dójú tì mí. info
التفاسير:

external-link copy
69 : 15

وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَلَا تُخۡزُونِ

Kí ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe yẹpẹrẹ mi.” info
التفاسير:

external-link copy
70 : 15

قَالُوٓاْ أَوَلَمۡ نَنۡهَكَ عَنِ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Wọ́n wí pé: “Ǹjẹ́ àwa kò ti kọ̀ fún ọ (nípa gbígba àlejò) àwọn ẹ̀dá?” info
التفاسير: