1. Ọ̀rọ̀ pọ̀ lórí ìtúmọ̀ “hād” àti ohun tó dúró fún nínú āyah yìí nínú àwọn tírà Tafsīr. Mẹ́ta nínú àwọn ìtúmọ̀ “hād” nínú āyah nìyí: (1) “hād” túmọ̀ sí “Allāhu”, ìyẹn ni pé, “Allāhu ni olùtọ́sọ́nà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan”. (2) “hād” túmọ̀ sí “Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ìyẹn ni pé, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni olùpèpè fún àwọn ènìyàn. (3) “hād” túmọ̀ sí “Ànábì kọ̀ọ̀kan”, ìyẹn ni pé, Ànábì kọ̀ọ̀kan ni olùpèpè fún ìjọ Ànábì kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ sá, kò sí tírà Tafsīr kan kan tí ó túmọ̀ āyah náà lọ síbi sísọ pé, “ànábì kan wà fún ọmọ Yorùbá” tàbí sísọ pé “ànábì kan wà fún ilẹ̀ Haúsá”. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūnus 10; 47.