1. Nínú èdè Lárúbáwá, “hamd” yàtọ̀ sí “ṣukr” àmọ́ ìtúmọ̀ ìkíní kejì fẹ́ súnmọ́ ara wọn. Ìtúmọ̀ “hamd” ni “ẹyìn” èyí tí a sọ jáde ní ẹnu pẹ̀lú ìfẹ́ àti gbígbé-títóbi fún ẹni tí ẹyìn tọ́ sí nítorí pé ẹni náà jẹ́ ẹni tí ó pé tán pátápátá tí kò kù sí ibì kan kan níbi pàápàá rẹ̀, àwọn ìròyìn rẹ̀ àti àwọn ìṣe rẹ̀. Kò sì sí ẹni tí ó pé tán pátápátá bí kò ṣe Allāhu - Ọba tó ga jùlọ -. Nítorí náà, Allāhu nìkan ṣoṣo ni a gbọ́dọ̀ máa yìn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ pé, Òun nìkan náà ni a gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. 2. Ọ̀rọ̀ yìí “rọbb” (Olúwa), ó kó ọ̀rọ̀ mẹ́ta sínú. Dídá ẹ̀dá, ṣíṣe ìjọba lórí ẹ̀dá tàbí níni ẹ̀dá àti dídarí ọ̀rọ̀ ẹ̀dá. Nígbà tí a bá pe Allāhu ní “rọbb” (Olúwa), gbogbo ìwọ̀nyẹn ló kó sínú nítorí pé, Allāhu ni Ẹlẹ́dàá wa, tiRẹ̀ ni ìjọba lórí gbogbo ẹ̀dá, Òun sì ni Ó ń darí kádàrá ẹ̀dá. Nítorí náà, Allāhu ni Olúwa wa.
1. Èyí ni àdéhùn ojoojúmọ́ tí à ń ṣe fún Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa àdéhùn náà, ó ti di ẹlẹ́bọ pọ́nńbélé títí ó fi máa ronú pìwàdà.
Allāhu - Ọba tó ga jùlọ - fi "bismillāh" bẹ̀rẹ̀ tírà Rẹ̀ torí kí Ó lè fi tọ́ àwọn ẹrú Rẹ̀ sọ́nà pé kí wọ́n máa fi "bismillāh" bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ wọn àti àwọn ọ̀rọ̀ wọn láti lè fi wá ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ àti kòńgẹ́ rere Rẹ̀.