ߞߎ߬ߙߣߊ߬ ߞߟߊߒߞߋ ߞߘߐ ߟߎ߬ ߘߟߊߡߌߘߊ - ߦߙߏߓߊߞߊ߲ ߘߟߊߡߌߘߊ - ߊ߬ߓߎ߰-ߙߊ߬ߤ߭ߌ߯ߡߊ߫ ߡߌߞߊߌߟߎ߫

external-link copy
24 : 38

قَالَ لَقَدۡ ظَلَمَكَ بِسُؤَالِ نَعۡجَتِكَ إِلَىٰ نِعَاجِهِۦۖ وَإِنَّ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلۡخُلَطَآءِ لَيَبۡغِي بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٍ إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَقَلِيلٞ مَّا هُمۡۗ وَظَنَّ دَاوُۥدُ أَنَّمَا فَتَنَّٰهُ فَٱسۡتَغۡفَرَ رَبَّهُۥ وَخَرَّۤ رَاكِعٗاۤ وَأَنَابَ۩

(Ànábì Dāwūd) sọ pé: “Ó ti ṣàbòsí sí ọ nípa bíbèèrè abo ewúrẹ́ tìrẹ mọ́ àwọn abo ewúrẹ́ tirẹ̀. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn olùbáda-n̄ǹkanpọ̀, apá kan wọn máa ń tayọ ẹnu-ààlà lórí apá kan àfi àwọn tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Díẹ̀ sì ni wọ́n.” (Ànábì) Dāwūd sì mọ̀ dájú pé A kàn fi (ìbéèrè náà) ṣàdánwò fún òun ni. Nítorí náà, ó tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀ (nípa àìtẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹni-afẹ̀sùnkàn). Ó dojú bolẹ̀ láti forí kanlẹ̀. Ó sì ronú pìwàdà (sọ́dọ̀ Allāhu).[1] info

1. Kíyè sí i, àwọn ìtàn kan tí àwọn nasọ̄rọ̄ máa ń sọ nípa Ànábì Dāwūd - kí ọlà Allāhu máa bá a - pé gbígbà tí ó gba ìyàwó ẹnì kan nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, tí ó fi kún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún ìyàwó tirẹ̀ l’ó bí ìṣẹ̀lẹ̀ tó jẹyọ nínú āyah yìí. Kódà, àwọn tírà tafsīr kan mú ìtàn náà wá pẹ̀lú láì ṣọ̀fín-tótó rẹ̀. Àwọn olùtọpinpin ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kúkú ti tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n sì sọ pé, “Ìtàn àwọn ọmọ Isrọ̄’īl lásán ni gbogbo rẹ̀. Ìtàn irọ́ ni.

التفاسير: