1. Àwọn āyah wọ̀nyí 144, 149 àti 150 ń pa wá láṣẹ láti dojúkọ agbègbè Kaabah lórí ìrun, ìyẹn sì ni agbègbè tí Kaabah wà sí ìlú ẹnì kọ̀ọ̀kan tàbí mọ́sálásí ẹnì kọ̀ọ̀kan. Ohun tó bí “agbègbè” dípò “ọ̀gangan” Kaabah ni pé, kò lè rọrùn rárá fún àwọn tí kò sí nínú mọ́sálásí Haram Mọkkah láti dojúkọ ọ̀gangan Kaabah láti àyè mìíràn lórí ìrun wọn.