1. Kókó āyah yìí ni pé, ó ń pàrọwà fún aláṣẹ obìnrin láti fọwọ́ wọ́nú lórí ìkọ̀sílẹ̀ ẹ̀ẹ̀ kíní tàbí ìkọ̀sílẹ̀ ẹ̀ẹ̀ kejì, pé kí ó tún yọ̀ǹda obìnrin tí ó jẹ́ alásẹ fún láti padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ bá ti wọ̀ padà láààrin ọkùnrin àti obìnrin náà.
1. Ìyẹn ni pé, bí àpẹ̀ẹrẹ, kí bàbá kú níkété tí ìyàwó rẹ̀ bímọ tán, kò sì sí ogún kan dàbí alárà nílẹ̀ tí ó fi sílẹ̀ fún ọmọ rẹ̀, àmọ́ ọmọ yìí ní àwọn ẹ̀gbọ́n níwájú àti bàbáabàbá ní àwọn tó jẹ́ pé, wọ́n wà nínú àwọn tí ó lè jogún ọmọdé yìí bí ó bá jẹ́ pé, ó kú ṣíwájú wọn, tí ó sì fi ogún sílẹ̀. Nítorí náà, àwọn náà ni wọ́n máa dìjọ máa dá owó ìfọ́mọlọ́yàn fún obìnrin tí wọ́n gbà fún iṣẹ́ ìfọ́mọlọ́yàn lórí òdiwọ̀n ìpín ogún tí ó lè kan ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn.