1. Nínú òfin tí Allāhu gbékalẹ̀ lórí olè ní àsìkò Ànábì Ya'ƙūb - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni pé, tí ọwọ́ bá tẹ olè, wọ́n máa fà á lé olóhun lọ́wọ́, ó sì máa sọ ọ́ di ẹrú rẹ̀. Àmọ́ ní àsìkò Ànábì tiwa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ọrùn ọwọ́ olè ni wọ́n máa gé pẹ̀lú àwọn májẹ̀mu rẹ̀.
1. Kò sí òfin sísọ olè dí ẹrú olóhun nínú ìlú Misrọ. Àmọ́ Allāhu fẹ́ kí Ànábì Yūsūf - kí ọlà Allāhu máa bá a - mú ọmọ ìyá rẹ̀ mọ́lẹ̀. Allāhu sì fi ìdàjọ́ tí wọ́n máa lò fún "olè" sí ẹnu àwọn ọmọ Ànábì Ya'ƙūb - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Ohun tí Allāhu fẹ́ sì wá sí ìmúṣẹ. 2. Ìyẹn ni pé, ẹ̀dá fi ipò àti ìmọ̀ ga jura wọn títí ipò àti ìmọ̀ fi pin sí ọ̀dọ̀ Allāhu Ọba tí Ó ga jùlọ nínú ipò àti ìmọ̀.