ߞߎ߬ߙߣߊ߬ ߞߟߊߒߞߋ ߞߘߐ ߟߎ߬ ߘߟߊߡߌߘߊ - ߦߙߏߓߊߞߊ߲ ߘߟߊߡߌߘߊ - ߊ߬ߓߎ߰-ߙߊ߬ߤ߭ߌ߯ߡߊ߫ ߡߌߞߊߌߟߎ߫

ߞߐߜߍ ߝߙߍߕߍ:close

external-link copy
54 : 11

إِن نَّقُولُ إِلَّا ٱعۡتَرَىٰكَ بَعۡضُ ءَالِهَتِنَا بِسُوٓءٖۗ قَالَ إِنِّيٓ أُشۡهِدُ ٱللَّهَ وَٱشۡهَدُوٓاْ أَنِّي بَرِيٓءٞ مِّمَّا تُشۡرِكُونَ

A kò níí sọ n̄ǹkan kan (sí ọ) bí kò ṣe pé, àwọn kan nínú àwọn òrìṣà wa ti fi aburú kan kàn ọ́ (ló fi ń sọ ìsọkúsọ nípa wọn).” Ó sọ pé: “Dájúdájú èmi ń fi Allāhu ṣe Ẹlẹ́rìí àti pé kí ẹ̀yin náà jẹ́rìí pé dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ info
التفاسير:

external-link copy
55 : 11

مِن دُونِهِۦۖ فَكِيدُونِي جَمِيعٗا ثُمَّ لَا تُنظِرُونِ

dípò jíjọ́sìn fún Allāhu. Nítorí náà, ẹ parapọ̀ déte sí mi. Lẹ́yìn náà, kí ẹ má ṣe lọ́ mi lára. info
التفاسير:

external-link copy
56 : 11

إِنِّي تَوَكَّلۡتُ عَلَى ٱللَّهِ رَبِّي وَرَبِّكُمۚ مَّا مِن دَآبَّةٍ إِلَّا هُوَ ءَاخِذُۢ بِنَاصِيَتِهَآۚ إِنَّ رَبِّي عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ

Dájúdájú èmi gbáralé Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín. Kò sí ẹ̀dá abẹ̀mí kan àfi kí (ó jẹ́ pé) Òun l’Ó máa fi àásó orí rẹ̀ mú un. Dájúdájú Olúwa mi wà lórí ọ̀nà tààrà. info
التفاسير:

external-link copy
57 : 11

فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَقَدۡ أَبۡلَغۡتُكُم مَّآ أُرۡسِلۡتُ بِهِۦٓ إِلَيۡكُمۡۚ وَيَسۡتَخۡلِفُ رَبِّي قَوۡمًا غَيۡرَكُمۡ وَلَا تَضُرُّونَهُۥ شَيۡـًٔاۚ إِنَّ رَبِّي عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٍ حَفِيظٞ

Nítorí náà, tí ẹ bá pẹ̀yìn dà (níbi òdodo), mo kúkú ti fi ohun tí Wọ́n fi rán mi níṣẹ́ jíṣẹ́ fún yín, Olúwa mi yó sì fi ìjọ kan tó máa yàtọ̀ sí ẹ̀yin rọ́pò yín. Ẹ kò sì lè kó ìnira kan kan bá A. Dájúdájú Olúwa mi ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.” info
التفاسير:

external-link copy
58 : 11

وَلَمَّا جَآءَ أَمۡرُنَا نَجَّيۡنَا هُودٗا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ بِرَحۡمَةٖ مِّنَّا وَنَجَّيۡنَٰهُم مِّنۡ عَذَابٍ غَلِيظٖ

Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Hūd àti àwọn tó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa; A gbà wọ́n là nínú ìyà tó nípọn. info
التفاسير:

external-link copy
59 : 11

وَتِلۡكَ عَادٞۖ جَحَدُواْ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِمۡ وَعَصَوۡاْ رُسُلَهُۥ وَٱتَّبَعُوٓاْ أَمۡرَ كُلِّ جَبَّارٍ عَنِيدٖ

Ìran ‘Ād nìyẹn; wọ́n tako àwọn āyah Olúwa wọn. Wọ́n sì yapa àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì tẹ̀lé àṣẹ gbogbo àwọn aláfojúdi alátakò-òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
60 : 11

وَأُتۡبِعُواْ فِي هَٰذِهِ ٱلدُّنۡيَا لَعۡنَةٗ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ أَلَآ إِنَّ عَادٗا كَفَرُواْ رَبَّهُمۡۗ أَلَا بُعۡدٗا لِّعَادٖ قَوۡمِ هُودٖ

A fi ègún tẹ̀lé wọn nílé ayé yìí àti ní Ọjọ́ Àjíǹde. Gbọ́, dájúdájú ìran ‘Ād ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Kíyè sí i, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ máa jẹ́ ti ìran ‘Ād, ìjọ (Ànábì) Hūd. info
التفاسير:

external-link copy
61 : 11

۞ وَإِلَىٰ ثَمُودَ أَخَاهُمۡ صَٰلِحٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥۖ هُوَ أَنشَأَكُم مِّنَ ٱلۡأَرۡضِ وَٱسۡتَعۡمَرَكُمۡ فِيهَا فَٱسۡتَغۡفِرُوهُ ثُمَّ تُوبُوٓاْ إِلَيۡهِۚ إِنَّ رَبِّي قَرِيبٞ مُّجِيبٞ

(Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran Thamūd ni arákùnrin wọn, (Ànábì) Sọ̄lih. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Òun l’Ó pílẹ̀ ìṣẹ̀dá yín láti ara (erùpẹ̀) ilẹ̀. Ó sì fún yín ní ìṣẹ̀mí lò lórí rẹ̀. Nítorí náà, ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Olúwa mi ni Olùsúnmọ́, Olùjẹ́pè (ẹ̀dá).” info
التفاسير:

external-link copy
62 : 11

قَالُواْ يَٰصَٰلِحُ قَدۡ كُنتَ فِينَا مَرۡجُوّٗا قَبۡلَ هَٰذَآۖ أَتَنۡهَىٰنَآ أَن نَّعۡبُدَ مَا يَعۡبُدُ ءَابَآؤُنَا وَإِنَّنَا لَفِي شَكّٖ مِّمَّا تَدۡعُونَآ إِلَيۡهِ مُرِيبٖ

Wọ́n wí pé: “Sọ̄lih, o ti wà láààrin wa ní ẹni tí a ní ìrètí sí (pé o máa sanjọ́) ṣíwájú (ọ̀rọ̀ tí o sọ) yìí. Ṣé o máa kọ̀ fún wa láti jọ́sìn fún ohun tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún ni? Dájúdájú àwa mà wà nínú iyèméjì tó gbópọn nípa n̄ǹkan tí ò ń pè wá sí.” info
التفاسير: