1. Ìyẹn ni pé, wọn kò níí dín ẹ̀san iṣẹ́ rere onígbàgbọ́ òdodo kù, wọn kò sì níí fi kún àṣìṣe rẹ̀. Àti pé, àforíjìn Allāhu súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí lórí àwọn àṣìṣe náà.
1. Nínú ìtúmọ̀ mìíràn fún āyah yìí kalmọh “mọsājid” dúró fún àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀. Àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀ ni iwájú orí àti góńgórí imú, àtẹ́lẹwọ́ méjéèjì, orúnkún méjéèjì àti orí ọmọníkasẹ̀ méjéèjì. Èèwọ̀ ni fún ẹ̀dá lati fi ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀ wọ̀nyí jọ́sìn tàbí kí ẹnikẹ́ni.
1. Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni òpin àwọn Ànábì àti òpin àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Kò sí àáfà kan kan tí Allāhu ń fi iṣẹ́ ìmísí rán mọ́. aṣ-Ṣaetọ̄n àlùjànnú ni àwọn àáfà tó ń woṣẹ́ bá dòwò pọ̀. Òjíṣẹ́ àlùjànnú ni irú wọn, wọn kì í ṣe “òjíṣẹ́ Ọlọ́hun”.