1. Ìtúmọ̀ “ wa ’an tẹstẹƙsimū bil ’azlām” ni pé “ (Èèwọ̀ sì ni fún yín láti fi àwọn ọfà kékeré mọ ìpín oore àti aburú yín nínú kádàrá yín.” Ìyẹn ni mo túmọ̀ ní ṣókí pé (Èèwọ̀ sì ni fún yín láti yẹṣẹ́ wò). 2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:173.
1. Ìyẹn nígbà tí ẹ bá fẹ́ rán ẹranko tàbí ẹyẹ láti dọdẹ àti nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹ ẹran tí ó pa fún yín.
1. Kíyè sí i, ìyẹn kì í ṣe oúnjẹ ìjọ́sìn àti oúnjẹ ọdún wọn. 2. Kíyè sí i, kò sí ìgbà kan kan tí Allāhu yọ̀ǹda fún obìnrin mùsùlùmí láti fẹ́ yẹhudi tàbí nasọ̄rọ̄, 3. Ìyẹn ni pé, mùsùlùmí kò gbọ́dọ̀ ti ìpasẹ̀ jíjẹ oúnjẹ onítírà àti fífẹ́ onítírà obìnrin di kèfèrí.