വിശുദ്ധ ഖുർആൻ പരിഭാഷ - യോറുബൻ വിവർത്തനം - അബൂ റഹീമ മീകാഈൽ

An-Nam'l

external-link copy
1 : 27

طسٓۚ تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡقُرۡءَانِ وَكِتَابٖ مُّبِينٍ

Tọ̄ sīn. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah al-Ƙur’ān àti (àwọn āyah) Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá. info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

التفاسير:

external-link copy
2 : 27

هُدٗى وَبُشۡرَىٰ لِلۡمُؤۡمِنِينَ

(Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìró ìdùnnú fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo, info
التفاسير:

external-link copy
3 : 27

ٱلَّذِينَ يُقِيمُونَ ٱلصَّلَوٰةَ وَيُؤۡتُونَ ٱلزَّكَوٰةَ وَهُم بِٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ يُوقِنُونَ

àwọn tó ń kírun, tí wọ́n ń yọ zakāh. Àwọn sì ni wọ́n ní àmọ̀dájú nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 27

إِنَّ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ زَيَّنَّا لَهُمۡ أَعۡمَٰلَهُمۡ فَهُمۡ يَعۡمَهُونَ

Dájúdájú àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́, A ti ṣe àwọn iṣẹ́ (aburú ọwọ́) wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn, Nítorí náà, wọn yó sì máa pa rìdàrìdà. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 27

أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ لَهُمۡ سُوٓءُ ٱلۡعَذَابِ وَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ هُمُ ٱلۡأَخۡسَرُونَ

Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí ìyà burúkú wà fún. Àwọn sì ni ẹni òfò jùlọ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 27

وَإِنَّكَ لَتُلَقَّى ٱلۡقُرۡءَانَ مِن لَّدُنۡ حَكِيمٍ عَلِيمٍ

Dájúdájú ò ń gba al-Ƙur’ān làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 27

إِذۡ قَالَ مُوسَىٰ لِأَهۡلِهِۦٓ إِنِّيٓ ءَانَسۡتُ نَارٗا سَـَٔاتِيكُم مِّنۡهَا بِخَبَرٍ أَوۡ ءَاتِيكُم بِشِهَابٖ قَبَسٖ لَّعَلَّكُمۡ تَصۡطَلُونَ

(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún àwọn ará ilé rẹ̀ pé: “Dájúdájú mo rí iná kan. Mo sì máa lọ mú ìró kan wá fún yín láti ibẹ̀, tàbí kí n̄g mú ògúnná kan tó ń tanná wá fún yín nítorí kí ẹ lè yẹ́ná. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 27

فَلَمَّا جَآءَهَا نُودِيَ أَنۢ بُورِكَ مَن فِي ٱلنَّارِ وَمَنۡ حَوۡلَهَا وَسُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Nígbà tí ó dé ibẹ̀, A pèpè pé kí ìbùkún máa bẹ fún ẹni tí ó wà níbi iná náà àti ẹni tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Mímọ́ sì ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
9 : 27

يَٰمُوسَىٰٓ إِنَّهُۥٓ أَنَا ٱللَّهُ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ

Mūsā, dájúdájú (ẹni tí ó ń bá ọ sọ̀rọ̀), Èmi ni Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
10 : 27

وَأَلۡقِ عَصَاكَۚ فَلَمَّا رَءَاهَا تَهۡتَزُّ كَأَنَّهَا جَآنّٞ وَلَّىٰ مُدۡبِرٗا وَلَمۡ يُعَقِّبۡۚ يَٰمُوسَىٰ لَا تَخَفۡ إِنِّي لَا يَخَافُ لَدَيَّ ٱلۡمُرۡسَلُونَ

Ju ọ̀pá rẹ sílẹ̀. (Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.) Àmọ́ nígbà tí ó rí i tó ń mira bí ẹni pé ejò ni, Mūsā pẹ̀yìndà, ó ń sá lọ. Kò sì padà sẹ́yìn. (Allāhu sọ pé:) Mūsā, má ṣe páyà. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ kì í páyà lọ́dọ̀ Mi. info
التفاسير:

external-link copy
11 : 27

إِلَّا مَن ظَلَمَ ثُمَّ بَدَّلَ حُسۡنَۢا بَعۡدَ سُوٓءٖ فَإِنِّي غَفُورٞ رَّحِيمٞ

Àyàfi ẹni tí ó bá ṣàbòsí,[1] lẹ́yìn náà tí ó yí i padà sí rere lẹ́yìn aburú. Dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. info

1. Kíyè sí i, àwọn ènìyàn tí kì í ṣe àwọn Ànábì àti Òjísẹ́ Allāhu - kí ọlà Allāhu máa bá wọn - ni gbólóhùn " Àyàfi ẹni tí ó bá ṣàbòsí" ń tọ́ka sí.

التفاسير:

external-link copy
12 : 27

وَأَدۡخِلۡ يَدَكَ فِي جَيۡبِكَ تَخۡرُجۡ بَيۡضَآءَ مِنۡ غَيۡرِ سُوٓءٖۖ فِي تِسۡعِ ءَايَٰتٍ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَقَوۡمِهِۦٓۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمٗا فَٰسِقِينَ

Ti ọwọ́ rẹ bọ igbá-àyà ẹ̀wù rẹ. Ó sì máa jáde ní funfun, tí kì í ṣe ti aburú. (Èyí wà) nínú àwọn àmì mẹ́sàn-án (tí o máa mú lọ) bá Fir‘aon àti àwọn ènìyàn rẹ̀. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
13 : 27

فَلَمَّا جَآءَتۡهُمۡ ءَايَٰتُنَا مُبۡصِرَةٗ قَالُواْ هَٰذَا سِحۡرٞ مُّبِينٞ

Nígbà tí àwọn àmì Wa tó fojú hàn kedere sì dé bá wọn, wọ́n wí pé: “Èyí ni idán pọ́nńbélé.” info
التفاسير: