ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

Nuuh

external-link copy
1 : 71

إِنَّآ أَرۡسَلۡنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوۡمِهِۦٓ أَنۡ أَنذِرۡ قَوۡمَكَ مِن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ

Dájúdájú Àwa rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀ pé: “Ṣèkìlọ̀ fún ìjọ rẹ ṣíwájú kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro tó dé bá wọn.” info
التفاسير:

external-link copy
2 : 71

قَالَ يَٰقَوۡمِ إِنِّي لَكُمۡ نَذِيرٞ مُّبِينٌ

Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín info
التفاسير:

external-link copy
3 : 71

أَنِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَٱتَّقُوهُ وَأَطِيعُونِ

pé kí ẹ jọ́sìn fún Allāhu, kí ẹ bẹ̀rù Rẹ̀, kí ẹ sì tẹ̀lé mi. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 71

يَغۡفِرۡ لَكُم مِّن ذُنُوبِكُمۡ وَيُؤَخِّرۡكُمۡ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمًّىۚ إِنَّ أَجَلَ ٱللَّهِ إِذَا جَآءَ لَا يُؤَخَّرُۚ لَوۡ كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ

(Allāhu) máa ṣàforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín fún yín. Ó sì máa lọ yín lára títí di gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú àkókò (ikú tí) Allāhu (kọ mọ́ ẹ̀dá), nígbà tí ó bá dé, wọn kò níí sún un ṣíwájú tí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀.” info
التفاسير:

external-link copy
5 : 71

قَالَ رَبِّ إِنِّي دَعَوۡتُ قَوۡمِي لَيۡلٗا وَنَهَارٗا

Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi pe ìjọ mi ní òru àti ní ọ̀sán. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 71

فَلَمۡ يَزِدۡهُمۡ دُعَآءِيٓ إِلَّا فِرَارٗا

Ìpè mi kò sì ṣe àlékún kan fún wọn àyàfi sísá sẹ́yìn (fún òdodo). info
التفاسير:

external-link copy
7 : 71

وَإِنِّي كُلَّمَا دَعَوۡتُهُمۡ لِتَغۡفِرَ لَهُمۡ جَعَلُوٓاْ أَصَٰبِعَهُمۡ فِيٓ ءَاذَانِهِمۡ وَٱسۡتَغۡشَوۡاْ ثِيَابَهُمۡ وَأَصَرُّواْ وَٱسۡتَكۡبَرُواْ ٱسۡتِكۡبَارٗا

Àti pé ìgbàkígbà tí mo bá pè wọ́n pé kí O lè foríjìn wọ́n, wọ́n ń fi ọmọníka wọn dí etí wọn, wọ́n ń yíṣọ wọn borí, wọ́n ń takú (sórí ẹ̀ṣẹ̀), wọ́n sì ń ṣègbéraga gan-an. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 71

ثُمَّ إِنِّي دَعَوۡتُهُمۡ جِهَارٗا

Lẹ́yìn náà, dájúdájú èmí pè wọ́n pẹ̀lú ohùn òkè. info
التفاسير:

external-link copy
9 : 71

ثُمَّ إِنِّيٓ أَعۡلَنتُ لَهُمۡ وَأَسۡرَرۡتُ لَهُمۡ إِسۡرَارٗا

Lẹ́yìn náà, dájúdájú èmí kéde fún wọn, mo sì tún pè wọ́n ní ìdá kọ́ńkọ́. info
التفاسير:

external-link copy
10 : 71

فَقُلۡتُ ٱسۡتَغۡفِرُواْ رَبَّكُمۡ إِنَّهُۥ كَانَ غَفَّارٗا

Mo sì sọ pé, ẹ tọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín, dájúdájú Ó ń jẹ́ Aláforíjìn. info
التفاسير:

external-link copy
11 : 71

يُرۡسِلِ ٱلسَّمَآءَ عَلَيۡكُم مِّدۡرَارٗا

Ó máa rọ̀jò fún yín ní òjò púpọ̀, info
التفاسير:

external-link copy
12 : 71

وَيُمۡدِدۡكُم بِأَمۡوَٰلٖ وَبَنِينَ وَيَجۡعَل لَّكُمۡ جَنَّٰتٖ وَيَجۡعَل لَّكُمۡ أَنۡهَٰرٗا

Ó máa fi àwọn dúkìá àti àwọn ọmọkùnrin ràn yín lọ́wọ́. Ó máa ṣe àwọn ọgbà oko fún yín. Ó sì máa ṣe àwọn odò fún yín. info
التفاسير:

external-link copy
13 : 71

مَّا لَكُمۡ لَا تَرۡجُونَ لِلَّهِ وَقَارٗا

Kí ló mu yín tí ẹ kò páyà títóbi Allāhu? info
التفاسير:

external-link copy
14 : 71

وَقَدۡ خَلَقَكُمۡ أَطۡوَارًا

Ó sì kúkú ṣẹ̀dá yín láti ìrísí kan sí òmíràn (nínú oyún).[1] info

1. Ìyẹn ni pé, láti ìrísí àtọ̀ sí ìrísí ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà sí bááṣí ẹran.

التفاسير:

external-link copy
15 : 71

أَلَمۡ تَرَوۡاْ كَيۡفَ خَلَقَ ٱللَّهُ سَبۡعَ سَمَٰوَٰتٖ طِبَاقٗا

Ṣé ẹ kò wòye sí bí Allāhu ṣe dá àwọn sánmọ̀ méje ní ìpele ìpele ni? info
التفاسير:

external-link copy
16 : 71

وَجَعَلَ ٱلۡقَمَرَ فِيهِنَّ نُورٗا وَجَعَلَ ٱلشَّمۡسَ سِرَاجٗا

Ó sì ṣe òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀ sínú wọn. Ó tún ṣe òòrùn ní àtùpà. info
التفاسير:

external-link copy
17 : 71

وَٱللَّهُ أَنۢبَتَكُم مِّنَ ٱلۡأَرۡضِ نَبَاتٗا

Allāhu mu yín jáde láti ara erùpẹ̀ ilẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
18 : 71

ثُمَّ يُعِيدُكُمۡ فِيهَا وَيُخۡرِجُكُمۡ إِخۡرَاجٗا

Lẹ́yìn náà, Ó máa da yín padà sínú rẹ̀. Ó sì máa mu yín jáde tààrà. info
التفاسير:

external-link copy
19 : 71

وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَرۡضَ بِسَاطٗا

Allāhu ṣe ilẹ̀ fún yín ní ìtẹ́ info
التفاسير:

external-link copy
20 : 71

لِّتَسۡلُكُواْ مِنۡهَا سُبُلٗا فِجَاجٗا

nítorí kí ẹ lè tọ àwọn ojú ọ̀nà fífẹ̀ gbẹ̀gẹ̀dẹ̀ lórí rẹ̀.” info
التفاسير:

external-link copy
21 : 71

قَالَ نُوحٞ رَّبِّ إِنَّهُمۡ عَصَوۡنِي وَٱتَّبَعُواْ مَن لَّمۡ يَزِدۡهُ مَالُهُۥ وَوَلَدُهُۥٓ إِلَّا خَسَارٗا

(Ànábì) Nūh sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú wọ́n yapa mi. Wọ́n sì tẹ̀lé ẹni tí dúkìá rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ kò ṣe àlékún kan fún bí kò ṣe òfò. info
التفاسير:

external-link copy
22 : 71

وَمَكَرُواْ مَكۡرٗا كُبَّارٗا

Wọ́n sì déte ní ète tó tóbi.” info
التفاسير:

external-link copy
23 : 71

وَقَالُواْ لَا تَذَرُنَّ ءَالِهَتَكُمۡ وَلَا تَذَرُنَّ وَدّٗا وَلَا سُوَاعٗا وَلَا يَغُوثَ وَيَعُوقَ وَنَسۡرٗا

Wọ́n sì wí pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ fi àwọn òrìṣà yín sílẹ̀. Ẹ kò gbọ́dọ̀ fi òrìṣà Wadd, Suwā‘u, Yẹgūth, Yẹ‘ūƙ àti Nasr sílẹ̀.” info
التفاسير:

external-link copy
24 : 71

وَقَدۡ أَضَلُّواْ كَثِيرٗاۖ وَلَا تَزِدِ ٱلظَّٰلِمِينَ إِلَّا ضَلَٰلٗا

Dájúdájú wọ́n ti kó ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ṣìnà. (Olúwa mi) má ṣe jẹ́ kí àwọn alábòsí lékún ní kiní kan bí kò ṣe ìṣìnà. info
التفاسير:

external-link copy
25 : 71

مِّمَّا خَطِيٓـَٰٔتِهِمۡ أُغۡرِقُواْ فَأُدۡخِلُواْ نَارٗا فَلَمۡ يَجِدُواْ لَهُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ أَنصَارٗا

Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. Wọ́n sì máa fi wọ́n sínú Iná. Wọn kò sì níí rí àwọn alárànṣe kan fún wọn lẹ́yìn Allāhu. info
التفاسير:

external-link copy
26 : 71

وَقَالَ نُوحٞ رَّبِّ لَا تَذَرۡ عَلَى ٱلۡأَرۡضِ مِنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ دَيَّارًا

(Ànábì) Nūh tún sọ pé: “Olúwa mi, má ṣe fi ẹnì kan kan nínú àwọn aláìgbàgbọ́ sílẹ̀ lórí ilẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
27 : 71

إِنَّكَ إِن تَذَرۡهُمۡ يُضِلُّواْ عِبَادَكَ وَلَا يَلِدُوٓاْ إِلَّا فَاجِرٗا كَفَّارٗا

Dájúdájú tí Ìwọ bá fi wọ́n sílẹ̀, wọn yóò kó ìṣìnà bá àwọn ẹrú Rẹ. Wọn kò sì níí bí ọmọ kan àfi ẹni burúkú, aláìgbàgbọ́. info
التفاسير:

external-link copy
28 : 71

رَّبِّ ٱغۡفِرۡ لِي وَلِوَٰلِدَيَّ وَلِمَن دَخَلَ بَيۡتِيَ مُؤۡمِنٗا وَلِلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِۖ وَلَا تَزِدِ ٱلظَّٰلِمِينَ إِلَّا تَبَارَۢا

Olúwa mi foríjìn èmi, àwọn òbí mi méjèèjì àti ẹni tó bá wọ inú ilé mi (tí ó jẹ́) onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Má sì ṣàlékún kan fún àwọn alábòsí àfi ìparun.” info
التفاسير: