ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

external-link copy
176 : 7

وَلَوۡ شِئۡنَا لَرَفَعۡنَٰهُ بِهَا وَلَٰكِنَّهُۥٓ أَخۡلَدَ إِلَى ٱلۡأَرۡضِ وَٱتَّبَعَ هَوَىٰهُۚ فَمَثَلُهُۥ كَمَثَلِ ٱلۡكَلۡبِ إِن تَحۡمِلۡ عَلَيۡهِ يَلۡهَثۡ أَوۡ تَتۡرُكۡهُ يَلۡهَثۚ ذَّٰلِكَ مَثَلُ ٱلۡقَوۡمِ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَاۚ فَٱقۡصُصِ ٱلۡقَصَصَ لَعَلَّهُمۡ يَتَفَكَّرُونَ

Àti pé tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá fi (ìmọ̀ nípa àwọn āyah Wa) ṣàgbéga fún un. Ṣùgbọ́n ó wayé mọ́yà. Ó sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀. Nítorí náà, àfiwé rẹ̀ dà bí ajá. Tí o bá lé e síwájú, ó máa yọ ahọ́n síta. Tí o bá sì fi sílẹ̀, ó tún máa yọ ahọ́n síta. Ìyẹn ni àfiwé ìjọ tó pe àwọn āyah Wa nírọ́. Sọ ìtàn náà fún wọn nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀. info
التفاسير: