1. Kíyè sí i! Ìtúmọ̀ “rūh” nínú āyah yìí ni ẹ̀rí òdodo, ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀nà. Àmọ́ ìtúmọ̀ “rūh” nínú sūrah an-Nisā’; 4:171, ìyẹn túmọ̀ sí ẹ̀mí tí Allāhu Ẹlẹ́dàá fi dá Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Bákan náà, “minhu” tí ó wà pẹ̀lú “rūh” nínú àwọn āyah méjèèjì túmọ̀ sí pé, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni ẹ̀rí òdodo (ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀nà) àti Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ti wá.