ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

external-link copy
116 : 5

وَإِذۡ قَالَ ٱللَّهُ يَٰعِيسَى ٱبۡنَ مَرۡيَمَ ءَأَنتَ قُلۡتَ لِلنَّاسِ ٱتَّخِذُونِي وَأُمِّيَ إِلَٰهَيۡنِ مِن دُونِ ٱللَّهِۖ قَالَ سُبۡحَٰنَكَ مَا يَكُونُ لِيٓ أَنۡ أَقُولَ مَا لَيۡسَ لِي بِحَقٍّۚ إِن كُنتُ قُلۡتُهُۥ فَقَدۡ عَلِمۡتَهُۥۚ تَعۡلَمُ مَا فِي نَفۡسِي وَلَآ أَعۡلَمُ مَا فِي نَفۡسِكَۚ إِنَّكَ أَنتَ عَلَّٰمُ ٱلۡغُيُوبِ

(Rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā ọmọ Mọryam, ṣé ìwọ l’o sọ fún àwọn ènìyàn pé: “Ẹ mú èmi àti ìyá mi ní ọlọ́hun méjì tí ẹ óò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu?” Ó sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ, kò tọ́ fún mi láti sọ ohun tí èmi kò lẹ́tọ̀ọ́ (sí láti sọ). Tí mo bá sọ bẹ́ẹ̀, O kúkú ti mọ̀. O mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí mi. Èmi ò sì mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Onímọ̀ nípa àwọn ìkọ̀kọ̀. info
التفاسير: