1. Ìyẹn ni pé, iṣẹ́ tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jẹ́ fún ayé kò yàtọ̀ sí ti àwọn tó ṣíwájú rẹ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -. Bákan náà, āyah náà ń pè wá síbi ìdúró ṣinṣin àti àtẹ̀mọra lásìkò ìnira àwọn aláìgbàgbọ́, àwọn tí kò tẹ̀lé ohun kan tayọ ìfẹ́-inú wọn.