ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

external-link copy
34 : 41

وَلَا تَسۡتَوِي ٱلۡحَسَنَةُ وَلَا ٱلسَّيِّئَةُۚ ٱدۡفَعۡ بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُ فَإِذَا ٱلَّذِي بَيۡنَكَ وَبَيۡنَهُۥ عَدَٰوَةٞ كَأَنَّهُۥ وَلِيٌّ حَمِيمٞ

Rere àti aburú kò dọ́gba. Fi èyí tí ó dára jùlọ dènà (aburú).[1] Nígbà náà ni ẹni tí ọ̀tá wà láààrin ìwọ àti òun máa dà bí ọ̀rẹ́ alásùn-únmọ́ pẹ́kípẹ́kí. info

1. Fífi rere dènà aburú ni ṣíṣe sùúrù pẹ̀lú ẹni tí ó ń bínú sí wa, ṣíṣe rere sí ẹni tí ó ń ṣe aburú sí wa, kíkí ẹni tí ó ń yàn wá lódì, ṣíṣe àtẹ̀mọ́ra pẹ̀lú ẹni tí ó ń hùwà àìmọ̀kan sí wa, wíwo ẹni tí ó ń ṣépè fún wa níran, wíwo ẹni tí ó ń bú wa níran àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

التفاسير: