1. Nínú dídarí àwọn āyah al-Ƙur’ān kọ ọ̀nà òdì ni fífún āyah kan ní ìtúmọ̀ òdì, fífi āyah kan tako āyah mìíràn, lílo āyah kan ní àyè tí kò jẹmọ́ ọn, fífi āyah kan ṣe ẹ̀fẹ̀, ṣíṣe àtakò sí āyah kan, pípa ọ̀rọ̀ al-Ƙur’ān tì láti tẹ̀lé ìròrí, ìṣe àti àṣà ìgbà-àìmọ̀kan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
1. Ìyẹn ni pé, kò sí tírà sánmọ̀ kan tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé irọ́ wà nínú al-Ƙur’ān ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ rẹ̀. Kò sì wulẹ̀ níí sí tírà kan kan mọ́ lẹ́yìn rẹ̀ láti sánmọ̀, áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa pe al-Ƙur’ān ní irọ́.
1. Ìyẹn ni pé, wọ́n ti sọnù jìnnà. Nítorí náà, wọn kò lè gbọ́ ìpè òdodo láti ọ̀nà jíjìn.