1. Ìtúmọ̀ rẹ̀ ni pé, ènìyàn wà ní ipò òkú nígbà tí ó jẹ́ aláìsí ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ìyẹn ṣíwájú ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ìyẹn ni ikú àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà, ó máa wà ní ipò alààyè nígbà tí ó bá délé ayé. Ìyẹn ni ìṣẹ̀mí àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà, ó máa di aláìsí nígbà tí ó bá parí òǹkà àkókò tí Allāhu pèbùbù fún un láti lò nílé ayé. Ìyẹn sì ni ikú kejì. Lẹ́yìn náà, ó máa di alààyè ní ọjọ́ Àjíǹde, kò sì níí kú mọ́. Ìyẹn sì ni ìṣẹ̀mí kejì.
1. Kíyè sí n̄ǹkan kan tó lágbára nínú āyah yìí nítorí kí o má baà di kèfèrí. Gbólóhùn yìí, “Ó ń fi ìmísí mímọ́ ránṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ sí ẹni = = tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀”, ìṣe yìí ti dópin nípasẹ̀ bí Allāhu ti ṣe fi Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ṣe òpin gbogbo àwọn tí ó gba ìmísí mímọ́ náà. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah al-’Ahzāb; 33:40. Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá tún sọ pé, òun náà wà nínú ẹni tí Allāhu fẹ́ fún rírí ìmísí mímọ́ gbà, òpùrọ́ asòòkùn sẹ́sìn ni onítọ̀ún.